Alaboyun meji fẹẹ gbe ẹgboogi oloro sọda n’Ikẹja, ọwọ ti tẹ wọn

Faith Adebọla

Loootọ ni wọn lawọn obinrin afurasi ọdaran meji yii, Ṣeun Babatunde ati Chikwendu Nworie Philip, diwọ disẹ sinu, ṣugbọn ofin ko mọ alaboyun yatọ, ọwọ awọn agbofinro ti tẹ wọn nibi ti wọn ti fẹẹ gbe egboogi oloro kọja ni papakọ ofufuru ilẹ wa n’Ikẹja, l’Ekoo.
Ẹni to kọkọ ko sakolo awọn agbofinro naa ninu awọn alaboyun ọhun ni Abilekọ Chikwendu Nworie, orileede Brazil lo n gbe, o si ba baaluu Qartar Airways kan to kero wa latilu Sao Paulo, lorileede naa, de lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu Karun-un, ta a wa yii.
Bi wọn ṣe n yẹ ẹru awọn arinrin-ajo naa wo ni papakọ ofururu Muritala Mohammed, n’Ikẹja, lati ri i daju pe ko sẹni to kẹru ofin wọlu, wọn ri paali alawọ pupa foo kan, wọn si ri i pe bata perẹsẹ tawọn obinrin n wọ lo wa ninu ẹ, ṣugbọn lasiko ti wọn n yẹ bata naa wo, egboogi oloro ti wọn pe ni kokeeni lo wa nibẹ, wọn di i bii bata pẹrẹsẹ ni.
Bi wọn ṣe n ṣewadii nipa ẹru ofin yii ni wọn tun ba kokeeni mi-in ti wọn di sinu awọn paali kan ti wọn n ko bata si. Abarebabọ, kokeeni ti wọn di sọna mẹrin naa jẹ iwọn ẹgbẹrin kilogiraamu (800 kg).
Nigba ti wọn bi Chikwendu leere ibi to ti ri egboogi oloro naa, o ni iṣẹ gẹrigẹri loun n ṣe ni Sao Paulo, ni Brazil, o loun wa si Naijiria lati waa sinku baba oun to doloogbe niluu awọn ni, ṣugbọn o jẹwọ pe oun loun gbe egboogi oloro naa lati le fi wa owo diẹ, tori ọwọ ọlọwọ, ẹsẹ ẹlẹsẹ, loun fi ri owo ọkọ baaluu toun wọ wa, oun si gbọdọ da owo toun ya lati fi ṣenawo oku pada, ati pe ọrẹ oun kan lọhun-un lo ni koun ba oun ko awọn egboogi naa fẹnikan l’Ekoo.
Wọn ti sọ ọ si gbaga awọn ẹṣọ ajọ NDLEA.
Lọjọ keji to tẹle e, iyẹn Wẹsidee, ejẹnti kan, Ṣọla Ogunrinde, gbe awọn paali ẹru kan wa, o loun fẹẹ ba kọsitọma oun fi ṣọwọ siluu Dubai, lorileede United Arab Emirate. Awọn nnkan mimu ẹleri-dodo ati ọti lile lo ko sinu paali ọhun, ṣugbọn nigba ti wọn ṣayẹwo finni-finni, ẹgboogi oloro lo fi tẹlẹ awọn paali ẹru ọhun.
Bi iṣẹ iwadii ṣe n tẹsiwaju, o jẹwọ pe Abilekọ Ṣeun Babatunde to n ta paraga ati siga ni ibudokọ Pleasure, to wa nitosi Iyana-Ipaja, l’Ekoo, lo ran oun niṣẹ. Oju-ẹsẹ ni wọn ti lọọ fi pampẹ ofin gbe obinrin naa, bo tilẹ jẹ pe alaboyun ni. Wọn tu awọn paali ẹru naa niṣeju rẹ, wọn si ba egboogi oloro ti wọn pe ni igbo, ọna meje lo di wọn si. Wọn tun ba egboogi oloro oriṣii mi-in ti wọn pe ni MDMA ninu agolo ọti amaraya-gaga Black Bullet. Babatunde oniparaga jewọ pe ọkọ oun to wa lorileede Dubai loun fẹẹ fi awọn ẹru ofin naa ṣọwọ si.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ karun-un, oṣu Karun-un, lọwọ ba alaboyun keji, nigba to fẹẹ wọ baaluu Turkish Airline kan to n lọ siluu Bolonia, lorileede Spain. Nigba ti wọn yẹ ẹru to fẹẹ gbe rinrin-ajo wo, wọn ba ọọdunrun koro egboogi Tramadol tijọba ti fofin de, aarin ede ati awọn nnkan eelo isebẹ lo tọju ẹ si, ni wọn ba mu un.
Iwadii ṣi n tẹsiwaju lori awọn afurasi ọdaran wọnyi gẹgẹ bi Alukoro apapọ fun ajọ to n gbogun ti okoowo egboogi oloro, NDLEA, Ọgbẹni Wilson Uwajuren, ṣe wi ninu atẹjade to fi lede lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹjọ, oṣu Karun-un yii.
O lawọn afurasi naa maa foju bale-ẹjọ tiwadii ba ti pari.

Leave a Reply