Alawada ni oṣiṣẹ to ba gba ipo tuntun lọwọ Oyetọla

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, ti bura fun awọn oṣiṣẹ ijọba ọgbọn (30) ti wọn yan sipo akọwe agba.

Atẹjade kan ti olori awọn oṣiṣẹ l’Ọṣun, Dokita Olowogboyega Oyebade, gbe jade lo kọkọ kede yiyan awọn akọwe agba naa, ti gomina si bura fun wọn nirọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kerinlelogun, oṣu Kọkanla yii.

Lara awọn akọwe agba tuntun ti wọn bura fun ni Agbẹjọro Bukọla Aderibigbe, Oyeṣiku Adelu, Ajibọla Falode ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ṣugbọn gomina tuntun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, nipasẹ akọwe iroyin ipolongo rẹ, Ọlawale Rasheed, ti sọ pe ofo ọjọkeji ọja ni iyansipo naa.

Bẹẹ ni wọn kilọ fun awọn akọwe agba tuntun naa lati ma ṣe tẹri si ẹbun ofeege ọhun nitori lẹyin ti wọn ba ti bura fun Adeleke ni yoo fi ọwọ osi juwe ile fun gbogbo wọn.

Atẹjade naa fi kun un pe ṣe ni Oyetọla mọ-ọn-mọ pinnu lati gbẹ koto gbese silẹ fun gomina tuntun, gbogbo igbesẹ to yẹ ko ti gbe lati ọdun mẹrin sẹyin lo ṣẹṣẹ n gbe lẹyin to lulẹ ninu idibo gomina.

O ni ṣe nijọba tuntun yoo ka oṣiṣẹ ijọba to ba gba ipo akọwe agba naa kun ẹni to gba ipo oṣelu, to si jẹ pe bii ẹni to gba ipo oṣelu ni, bii ẹni to yan an sipo ba ti n lọ loun naa yoo tẹle e. O fi kunn un pe bi wọn ba ti ṣebura fun Adeleke lọjo Aiku, to ba ti wọṣẹ lọjọ Aje, gbogbo aọn iyansipo yii ni yoo fagi le.

Leave a Reply