Alima yii ti ha o, awọn akẹkọọ ileewe alakọọbẹrẹ mẹta lo ji gbe l’Ekoo

Adewale Adeoye

Ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Ijegun, nipinlẹ Eko, ni iyaale ile kan, Abilekọ Akintọla Alima, ẹni ogoji ọdun, ti wọn fẹsun ijinigbe kan wa bayii. Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta,  ni ọwọ awọn agbofinro ilu Eko tẹ ẹ ninu ọgba ileewe alakọọbere kan to wa niluu Ijegun, nipinlẹ Eko, lasiko toun atawọn ẹmẹwaa rẹ ya wọbẹ, ti wọn si ji awọn akẹkọọ mẹta gbe lọ.

Orukọ ati ọjọ ori awọn akẹkọọ ileewe alakọọbẹrẹ  ti Alima ji gbe ni Sọfiat, ọmọ ọdun mẹrin, Isreal, ọmọ ọdun marun-un, ati Mustapha, ọmọ ọdun mẹfa.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹta aabọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni Alima atawọn ẹmẹwaa rẹ kan tawọn ọlọpaa n wa bayii ṣiṣẹ buruku ọhun.

Ṣa o, aṣiri awọn oniṣẹ ibi naa tu loju-ẹsẹ, nigba tawọn kan ṣakiyesi pe irin ẹsẹ wọn ko mọ. Awọn eeyan naa lo sare pe ọlọpaa pe ki wọn waa fọwọ ofin mu wọn. Gbara tawọn ọlọpaa de si agbegbe naa ni awọn yooku Alima ti sa lọ pẹlu ọkada kan ti ko ni nọmba idanimọ ti wọn gbe wa sinu ọgba ileewe alakọọbẹrẹ naa lati waa fi ṣiṣẹ ibi ọhun, ṣugbọn ọwọ tẹ Alima.

Wọn gba awọn ọmọ mẹta ọhun lọwọ rẹ, wọn si ti da wọn pada fawọn obi wọn loju-ẹsẹ.

Ọdọ awọn ọlọpaa ni Alima wa to fi jẹwọ pe loootọ iṣẹ ijinigbe loun atawọn ẹlẹgbẹ oun n ṣe ko too di pe ọwọ tẹ oun.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyon lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹta, ọdun yii, pe awọn ti n ṣiṣẹ takuntakun labẹnu lati fọwọ ofin mu awọn ọdaran yooku to jẹ ọrẹ Alima yii, tawọn si maa foju gbogbo wọn bale-ẹjọ lẹyin iwadii.

 

Leave a Reply