Lori iku Mohbad, awọn ọlọpaa ti ju Prime Boy satimọle o

Adewale Adeoye

Titi di asiko ta a n koroyin yii jọ, ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Panti, niluu Yaba, nipinlẹ Eko, ni Ọgbẹni Ibrahim Owodunni, ẹni tawọn eeyan mọ si Prime-Boy, ti i ṣe ọrẹ korikosun gbajumọ akọrin nni, Oloogbe Ilerioluwa Aloba, ẹni tawọn eeyan mọ si Mohbad wa.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹta yii, lo lọ sọdọ awọn ọlọpaa naa gẹgẹ bii adehun to wa laarin oun atawọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa Panti ti wọn n ṣewadii nipa iku Mohbad lọwọ.

Ohun ti wọn sọ fun un ni pe ko maa waa fara han lọdọ awọn lọsọọsẹ titi ti iwadii tawọn n ṣe lọwọ lori iku ọrẹ rẹ fi maa dopin Latigba ti wọn ti gba beeli rẹ lọdun to kọja yii ni Prime-Boy ti n lọ sileeṣẹ awọn ọlọpaa ọhun, ṣugbọn gbara toun ati ọrẹ rẹ kan, Ọgbẹni Ayọbami Fisayọ, ẹni tawọn eeyan mọ si Spending, yọju sileeṣẹ awọn ọlọpaa ọhun lọjọ Iṣẹgun yii ni wọn ti ko ṣẹkẹṣẹkẹ si i lọwọ, ti wọn si mu un wọle sinu ahaamọ wọn.

Ẹsun tuntun ti wọn ṣẹṣẹ fi kan Prime-Boy ni pe Ọmọwunmi ti i ṣe iyawo oloogbe waa fẹsun ọdaran kan an lọdọ awọn.

Ẹsun ti wọn ni iyawo oloogbe naa fi kan Prime-Boy ni pe aipẹ yii lo sọrọ ba oun lorukọ jẹ laarin ilu, ati pe Prime-Boy n dunkooko mọ oun nigba gbogbo lori iku ọkọ oun tawọn ọlọpaa n ṣewadii nipa rẹ bayii. Eyi, atawọn ẹsun iwa ọdaran mi-in ni wọn sọ pe iyawo oloogbe fi kan Prime-Boy.

Latigba ti Oloogbe Mohbad ti ku lọjọ kejila, oṣu Kẹjọ, ọdun to kọja yii, ni awọn araalu, paapaa ju lọ awọn ololufẹ rẹ ti n naka abuku si Prime-Boy atawọn kọọkan pe ọwọ wọn ko mọ lori iku to pa oloogbe naa.

Lara awọn ti ọlọpaa ti fọwọ ofin mu lori iṣẹlẹ ọhun ni gbajumọ akọrin nni, Naira Marley, Sam Larry atawọn kọọkan. Gbogbo awọn ti wọn mu yii pata ni wọn ti gba beeli wọn, ṣugbọn ọsẹ yii ni wọn ṣẹṣẹ tun fọwọ ofin mu Prime-Boy.

Ṣa o, wọn ti ni ki Spending, iyẹn ọrẹ Prime-Boy ti wọn jọọ wa sileeṣẹ awọn ọlọpaa ọhun maa lọ sile ni tiẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko S.P Benjami Hundeyn fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, O ni wọn maa too fi Prime-Boy silẹ lẹyin to ba ṣalaye ara rẹ fun wọn tan.

Leave a Reply