APC lo yege ibo alaga kansu ni gbogbo ijọba ibilẹ ogun nipinlẹ Ogun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ẹyọ kan ṣoṣo bayii ko ṣẹku ninu ijọba ibilẹ Ogun to wa nipinlẹ Ogun, eyi ti ẹgbẹ oṣelu APC ko mu ninu ibo ijọba ibilẹ ti wọn di lọjọ Satide to kọja yii, iyẹn fun ti awọn alaga ijọba ibilẹ. Gbogbo awọn to dupo ṣiamaanu wọn lo wọle pata.

Aarọ kutu ọjọ Sannde ti i ṣe ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu keje, ni Alaga ajọ eleto idibo Ogun, Ọgbẹni Babatunde Osibodu, ti kede pe ijọba ibilẹ mẹtadinlogun (17) ti ja mọ APC lọwọ nipo alaga, iyẹn ninu ijọba ibilẹ Ogun to wa nipinlẹ yii.

Nigba ti yoo fi di aago meji-aabọ ọsan ọjọ Sannde naa, Osibodu ti kede pe gbogbo ijọba ibilẹ Ogun pata ti ja mọ APC lọwọ fawọn alaga, ko si ẹgbẹ alatako kankan to rọwọ mu, awọn ondije lẹgbẹ APC ni kinni naa bọ si lọwọ gbogbo.

Alaga OGSIC ṣalaye pe apapọ ibo ti wọn di fun ipo alaga lawọn ijọba ibilẹ ogun nipinlẹ Ogun jẹ ẹgbẹrun lọna irinwo din mẹrin, ojilelẹgbẹta ati ẹyọ kan (396, 641).

O ni awọn yoo fi abajade ibo awọn kansilọ naa sita tawọn ba ṣetan.

O fi idunnu rẹ han si bi ibo naa ṣe lọ nirọwọ-rọsẹ, o si dupẹ lọwọ awọn eeyan ti wọn huwa ọmọluabi, ti idibo naa fi yọri si rere.

Bakan naa lo dupẹ lọwọ awọn agbofinro ti wọn ṣiṣẹ aabo lasiko ibo yii, o si rọ awọn ti wọn jawe olubori lati ṣe awọn ti wọn fidi rẹmi daadaa. Ki wọn ma ṣe ri wọn bii alatako.

Leave a Reply