Nitori Igboho, Olubadan ran ikọ lọ si orileede Benin

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ṣe owe Yoruba lo sọ pe ọmọ ẹni ko le ṣe idi bẹbẹrẹ ka fi ilẹkẹ sidii ọmọ ẹlomi-in, eyi lo difa fun Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Saliu Adetunji, Aje Ogungunnisọ, to fi ran awọn aṣoju lati ilẹ Ibadan lọ si orileede Olominira Benin, lati lọọ ṣabẹwo si Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho, ati lati mọ bi igbẹjọ ti yoo waye ni ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii yoo ṣe lọ si.

Lẹyin ipade awọn oloye ilu naa ti wọn ṣe nile Olubadan to wa ni Popo Yemọja, niluu Ibadan lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni igbesẹ yii waye.

Nigba ti ALAROYE pe Akọwe iroyin Olubadan, Ọgbẹni Adeọla Ọlọkọ lori foonu, ọkunrin naa fidi rẹ mulẹ fun akọroyin wa pe loootọ ni Kabiyesi ran awọn aṣoju lọ si orileede Benin lati mọ bi igbẹjọ naa ṣe n lọ si.

Olubadan ni igbesẹ yii waye lati fi ọkan awọn eeyan balẹ, paapaa awọn ti wọn n fẹhonu han lori ọrọ yii ati awọn ti wọn ro pe niṣe ni Olubadan kawọ gbera ti ko ṣe nnkan kan lori rẹ yii.

Kabiyesi ṣalaye pe ilu Ibadan ni Sunday n gbe, o bimọ s’Ibadan, ibẹ naa lo ti tọju awọn ọmọ rẹ, o niṣẹ aje s’Ibadan, o si jẹ ojuṣe ọba alaye yii lati daabo bo gbogbo awọn ti wọn ba wa ni akata rẹ labẹ ofin. Eyi naa lo si mu igbesẹ ti awọn fẹẹ gbe yii waye.

Nigba ti akọroyin wa beere iye awọn ti Kabiyesi ran lọ ati orukọ wọn, Ọlọkọ ni Kabiyesi ko fẹẹ darukọ awọn to ran lọ, bẹẹ ni ko si fẹẹ sọ iye wọn.

Ṣugbọn loootọ ni Olubadan ran awọn eeyan naa lọ si Benin lati wo bi igbẹjọ naa ṣe n lọ ati lati mọ boya wọn n tẹle ofin lorileede naa.

Nigba ti akọroyin wa ṣalaye fun agbẹnusọ ọba naa pe ẹnikẹni lo le lọ si ilẹ Benin lati lọọ wo igbejọ naa, ti a si beere pe njẹ awọn nnkan mi-in wa ti Kabiyesi ran wọn lati ṣe nibẹ, Ọlọkọ ni iṣẹ ti wọn ran wọn naa niyẹn.

Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni awọn to n fẹhonu han nipa bi wọn ṣe mu Oloye Sunday Igboho ya lọ si aafin Olubadan, ti wọn si rọ ọba alaye naa lati wa gbogbo ọna ki wọn le da Igboho silẹ lai gbe e wa si Naijiria. Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni igbẹjọ yoo tun waye lori ẹjọ ti wọn n ba a ṣe ni orileede Benin.

 

Leave a Reply