APC fa Monisade Afuyẹ kalẹ lati dupo igbakeji gomina l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ekiti

Wọn ti fi orukọ Abilekọ Monisade Christiana Afuyẹ to jẹ Olori awọn obinrin ẹgbẹ APC nipinlẹ Ekiti ranṣẹ si ajọ INEC gẹgẹ bii ẹni ti yoo dije papọ pẹlu Ọgbẹni Biọdun Oyebanji ti wọn fa kalẹ pe yoo ṣoju ẹgbẹ naa ninu eto idibo gomina ti yoo waye lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii.

Paul Ọmọtọṣọ to jẹ Alaga ẹgbẹ naa lo sọrọ yii di mimọ nipasẹ Alukoro ẹgbẹ APC l’Ekiti, Ọgbẹni Ṣẹgun Dipẹ.

O ṣalaye pe lẹyin ọpọlọpọ ifukunlukun pẹlu awọn alẹnulọrọ lawọn pinnu lati yan obinrin naa. O fi kun un pe awọn ti fi orukọ Afuyẹ ranṣẹ si ajọ eleto idibo, gbogbo igbesẹ to ku to yẹ lori eleyii lawọn ti gbe.

Atẹjade naa ka pe, ‘‘Ẹgbẹ oṣelu APC Ekiti n kede yiyan Abilekọ Monisade Christiana Afuyẹ gẹgẹ bii oludije sipo igbakeji gomina ninu eto idibo ti yoo waye lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹfa.

‘‘A ti fi ipinnu wa yii to ajọ eleto idibo leti, ni ibamu pẹlu awọn ilana ati ofin to rọ mọ eto idibo.

‘‘Ipinnu wa lati fa Afuyẹ kalẹ ni i ṣe pẹlu ipade loriṣiiriṣii pẹlu awọn alẹnulọrọ kaakiri ipinlẹ naa. Inu gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ lo si dun si igbesẹ yii, to fi mọ awọn ọdọ, awọn obinrin awọn iyalọja ati oniṣowo gbogbo, awọn ọba alaye atawọn eeyan igberiko kaakiri.

‘‘Inu wa dun pe gbogbo awọn eeyan wa lo tẹwọ gba obinrin yii gẹgẹ bii oludije.’’

Afuyẹ naa dupẹ lọwọ awọn aṣaaju ẹgbẹ, fun igbẹkẹle ti wọn ni ninu rẹ, bẹẹ lo ṣeleri pe oun ko ni i da ẹgbẹ naa.

O ni oun yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu gbogbo awọn to yẹ lati ri i pe ohun gbogbo lọ bo ṣe yẹ. Ni gbogbo igba lo ni ilẹkun oun yoo maa ṣi silẹ fun awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn ba ni ohunkohun lati sọ pẹlu oun.

Tẹ o ba gbagbe, obinrin ni Ayọdele Fayoṣe ti ẹgbẹ PDP naa fẹẹ fa kalẹ, Funmi Ogun lorukọ rẹ, oun ni kọmiṣanna tẹlẹ fun ọrọ iṣẹ nipinlẹ Ekiti, ṣugbọn obinrin naa naa ni oun ko fẹ ipo ti wọn fẹẹ yan oun si yii.

Leave a Reply