Believe Bọla
Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ti wọgi le apero gbogbogboo wọn to yẹ ko waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii si ọjọ mi-in ọjọọre.
Gomina ipinlẹ Yobe, to tun jẹ Alaga igbimọ kiateka to n ṣakoso ẹgbẹ naa lapapọ, Alaaji Mai Mala Buni, lo kede iyipada naa lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ninu lẹta kan ti Buni ati Akọwe ẹgbẹ wọn, Sẹnetọ John James Akpanudoedehe, kọ si Alaga ajọ eleto idibo ilẹ wa, (INEC), Mahmood Yakubu, lorukọ ẹgbẹ wọn.
Ninu lẹta ọhun, wọn lo pọn dandan lati sun apero ẹgbẹ naa siwaju ki wọn le raaye ṣeto idibo ẹlẹkunjẹkun ẹgbẹ wọn na. Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹta, ni wọn leto idibo ẹlẹkunjẹkun naa fẹẹ waye.
Ṣaaju asiko yii lolobo ti n ta awọn kan pe igbimọ kiateka fẹẹ sun apero naa siwaju, wọn ni oṣu kẹta ni wọn fẹẹ sun un si. Ẹnikan toun naa ti figba kan jẹ ọmọ igbimọ alakooso apapọ ẹgbẹ APC sọ pe: “Awọn nnkan to yẹ lati ṣe ṣi pọ gidi, ko si sọgbọn ti awọ yoo fi kaju ilu ki ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, ti wọn da yii too pe, tori ko ju ọsẹ kan lọ mọ bayii. Fun apẹẹrẹ, ọrọ ti pinpin ipo si agbegbe ti wọn fẹ kawọn oloye ẹgbẹ ti jade (eyi ti wọn n pe ni soni-in (zoning), ko ti i yanju. Awọn eeyan ko ra fọọmu lati dije, bawo si ni wọn ṣe le ra fọọmu, nigba ti wọn o ti i mọ ibi ti wọn ti fẹ kawọn eeyan jade du ipo kan ni pato. Iyẹn lo le jẹ ki wọn mọ fọọmu ipo ti wọn maa ra, ti wọn si maa dije fun. Teeyan o ba mọ soni-in, ko le ra fọọmu.
“Nnkan mi-in tun ni pe ko si awọn kọmiti to yẹ ko ti wa lẹnu iṣẹ fun ti apero yii, wọn o ti i yan wọn. O kere tan, mo ṣeranti pe nnkan bii igbimọ alabẹ ṣekele ogun (20) lo ṣiṣẹ nifọwọsowọpọ lasiko apero gbogbogboo ta a ṣe kẹyin, ko too yọri si rere. Ko ti i si imurasilẹ gun-unmọ kan, apero gbogbogboo si ni, ki i ṣe ọrọ ṣereṣere, ko si ṣee ṣe ni sare-n-ba’ja, aijẹ bẹẹ, niṣe ni gbogbo ẹ maa fori ṣanpọn.”
Bẹẹ lọkunrin naa sọ.
Tẹ o ba gbagbe, ọpọ igba ni wọn ti n sun apero naa siwaju latẹyinwa. Oṣu Kẹfa, ọdun 2020, ni Buhari ti yan igbimọ kiateka yii nigba ti nnkan polukurumuṣu lẹgbẹ oṣelu APC latari bile-ẹjọ ṣe yẹ aga mọ alaga wọn ana, Adams Oshiomhole, nidii lai ro ti, wọn ni ki wọn ṣeto apero gbogbogboo laarin oṣu mẹta.
Latigba naa ni igbimọ kiateka ti n sun apero naa siwaju, ti wọn si n beere aaye si i, bẹẹ ni Buhari n fun wọn.