Arẹgbẹṣọla sọ fawọn ọmọlẹyin rẹ: Ẹ ma ṣe jẹ ki ọkan yin daamu, a maa gba ẹtọ wa pada lọwọ Oyetọla

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Minisita fun ọrọ abẹle lorileede yii, Ọgbẹni Rauf Adesọji Arẹgbẹṣọla, ti sọ fun awọn ọmọlẹyin rẹ nipinlẹ Ọṣun lati ma ṣe bọkan jẹ rara latari esi idibo abẹle ẹgbẹ APC to waye nipinlẹ Ọṣun lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ  to kọja.

O ni ọpọlọpọ nnkan ti ko bojumu lo waye lasiko idibo naa, ṣugbọn awọn ko nilo lati banujẹ tabi ba ẹnikẹni fa wahala nitori awọn yoo lo ilana ofin lati fi gba ẹtọ awọn pada lọwọ Gomina Oyetọla.

A oo ranti pe Arẹgbẹṣọla ko yọju sibi eto idibo naa, bẹẹ ni Oyetọla jawe olubori ni gbogbo wọọdu awọn to ṣe ja-n-kan-ja-n-kan ninu igun TOP.

Amọ ṣa, ninu atẹjade kan ti Arẹgbẹṣọla fi sita nipasẹ Akọwe iroyin rẹ, Ṣọla Faṣure, lalẹ ọjọ Satide lo ti ka awọn oniruuru kudiẹ-kudiẹ to wa ninu eto idibo abẹlẹ naa.

O ni oun gbọ nipa iwa kebekebe ti awọn oṣiṣẹ ti wọn ṣeto idibo naa hu, bẹẹ si ni oun gbọ nipa bi wọn ṣe yọ orukọ awọn ti wọn jẹ ọmọ TOP kuro lara orukọ awọn oludibo. O sọ nipa bi awọn kan ṣe ti tọwọ bọ iwe iforukọsilẹ awọn ọmọ ẹgbẹ APC loju, ati bi ko ṣe si ayẹwo orukọ awọn oludibo lawọn wọọdu kan.

Arẹgbẹṣọla ni wọn n ha kaadi ọmọ ẹgbẹ fun awọn kan laaarọ yii lati le dibo fun Oyetọla, bẹẹ lo jẹ pe awọn abẹṣinkawọ gomina ni wọn n ṣakoso ibo, ti iye ibo ti wọn n ka fun Oyetọla si ju iye awọn ti wọn sạyẹwo kaadi wọn ki ibo too bẹrẹ lọ.

O ni ọpọ ibudo idibo ni ko ti si iwe abajade esi idibo, bẹẹ ni awọn ọmọ ajọ eleto idibo ko si ni ọpọ wọọdu.

Ju gbogbo rẹ lọ, Arẹgbẹṣọla parọwa si wọn lati ni suuru, ki wọn ma ṣe kanju, nitori awọn ti bẹrẹ si i ṣayẹwo abajade idibo naa, awọn yoo si gbe igbesẹ lori wọn laipẹ.

Leave a Reply