Atọlagbe yii buru o! Lẹyin to fipa ba obinrin kan sun tan lo ge ẹran ẹ wẹlẹwẹ, o ba dana sun un ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọtafa-soke yido-bori, b’ọba aye ko ri ọ, tọrun n wo ọ. Ọrọ ikilọ yii lo wọ bọwọ awọn agbofinro ṣe tẹ afurasi ọdaran kan, Atọlagbe Yẹmi Oje, to ṣeku pa obinrin kan, Mayọwa Ajiboye. Lẹyin to fipa ba a laṣepọ tan lo kun ẹran rẹ wẹlẹwẹ, o dana sun un, o si lọọ da eeru ẹ sodo niluu Àrán-Ọ̀rin, nipinlẹ Kwara.

Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, CP Victor Olaiya to ṣafihan awọn afurasi ọdaran yii lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, sọ pe ninu oṣu Kọkanla, ọdun to kọja yii, ni Mayọwa Ajiboye, to n gbe ile Àró-Olólà, niluu Àrán-Ọ̀rin, lọna Òmù-Àrán, nipinlẹ Kwara, mu ẹsun lọ si agọ ọlọpaa pe Atọlagbe Oje, gba ẹgbẹrun kan aabọ Naira lọwọ oun pẹlu adehun pe yoo lọọ ba oun ṣẹgi ninu igbo, ṣugbọn ti ko gbe igi naa wa, bẹẹ ni ko si da owo pada.

Ọga ọlọpaa ni lọjọ kejilelogun, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, ni Atọlagbe pade Mayọwa ati ọmọ rẹ, Ọpẹ, nibi ti wọn ti n ṣẹgi loko, lo ba dọgbọn darapọ mọ wọn, ti wọn si jọ n ṣẹgi ninu igbo. Ṣugbọn nigba to ya ni Atọlagbe ni ki Ọpẹ gbe igi lọ sibi ti wọn ti fẹẹ dana. Lasiko naa ni ọmọkunrin yii lagi mọ Iya Mayọwa lori, o fipa ba a laṣepọ.

Wọn ni lẹyin to ba a sun tan lo fi anki funfun nu oju ara rẹ, o fa irun abẹ oloogbe, o tun fi ọbẹ kun ara rẹ wẹlẹwẹlẹ, o dana sun un, o si lọọ da eeru ẹ sodo ki aṣiri ma baa tu.

Ni bayii ṣa, wọn  ti mu un, o si ti n ṣẹju pako lakolo ọlọpaa, nibi ti iwadii rẹ ti n tẹsiwaju.

Leave a Reply