Gende meji dero kootu l’Akurẹ, foonu ni wọn ji nibi eto isinku Akeredolu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ti wọ awọn afurasi ole meji kan, Oluṣẹyẹ Adefila ati Mọsuru Faṣọla, lọ sile-ẹjọ Majsireeti to wa lagbegbe Oke-Ẹda, niluu Akurẹ, fun jija awọn eeyan kan lole lasiko ti wọn n ṣẹyẹ ikẹyin fun gomina tẹlẹ nipinlẹ Ondo, Oloogbe Rotimi Akeredolu.

Awọn afurasi mejeeji yii la gbọ pe ọwọ awọn Amọtẹkun tẹ nibi ti wọn ti n ji foonu awọn alejo to wa sibi eto isinku naa yọ ni ṣọọṣi Anderu Mimọ, to wa niluu Ọwọ, nijọba ibilẹ Ọwọ, ni nnkan bii aago mejila ọsan ọjọ kẹtalelogun, oṣu Keji, ọdun 2024 ta a wa ninu rẹ yii.

Agbefọba, Amofin P. O. Nwafor, ṣalaye lasiko tawọn olujẹjọ ọhun n fara han nile-ẹjọ pe iwadii ti fidi rẹ mulẹ pe awọn afurasi ọhun ko niṣẹ mi-in ti wọn yan laayo ju ki wọn maa ja awọn eeyan lole nibikibi ti wọn ba ti n ṣayẹyẹ lọ.

O ni ọpọlọpọ foonu lawọn olujẹjọ ọhun ti kọkọ ji, ki wọn too tun lọọ ji ti ọmọbinrin kan torukọ rẹ n jẹ Elizabeth, ninu ṣọọṣi to jokoo si nigba ti wọn n ṣeto isinku Gomina Akeredolu lọwọ.

Nwafor ni ẹsun ifimọ-ṣọkan huwa to lodi sofin ati ole jija ti wọn fi kan awọn olujẹjọ mejeeji ta ko abala okoo le lẹẹẹdẹgbẹta din mẹrin (516) ati ẹẹdẹgbẹta le mẹsan-an (509) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.

Lọgan tawọn olujẹjọ yii ti lawọn ko jẹbi ẹsun mejeeji ti wọn fi kan wọn ni agbẹjọro wọn, Amofin A. Ilemobayọ, ti bẹbẹ fun gbigba beeli wọn pẹlu ileri pe awọn onibaara oun ti ṣetan lati wa oniduuro to ṣee fọkan tan lati duro fun wọn.

Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ Damilọla Ṣekoni, faaye beeli silẹ fun ọkọọkan awọn olujẹjọ pẹlu ẹgbẹrun lọna igba Naira, ki wọn si tun ri i daju pe awọn ṣeto oniduuro meji meji niye owo kan naa.

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii ni adajọ sun igbẹjọ mi-in si.

Leave a Reply