Ẹ woju awọn ọdaran ti wọn pa Rianat lasiko to fẹẹ lọọ ra kulikuli l’Ọffa

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Aṣe ootọ lowe Yoruba to ni iyan ogun ọdun a maa jo ni lọwọ fẹlifẹli. Eyi lo ṣe rẹgi pẹlu bi ileesẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ṣe ṣafihan awọn afurasi afini ṣowo meji kan, Fẹmi Adeniji ati Shittu Abdulmalik Wale. Wọn ni awọn mejeeji yii ni wọn pa ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹẹẹdogun kan, Yusuf Rianat, lasiko ti wọn ran an ko lọọ ra kulikuli ti wọn fẹẹ fi mu gaari wa ni agbegbe Amuyọ, niluu Ọffa, nijọba ibilẹ Ọffa, nipinlẹ Kwara, lọdun 2021. Lẹyin ti wọn pa a tan ni wọn kun un wẹlẹwẹlẹ, wọn si ta apa rẹ ni ẹgbẹrun lọna ogun Naira fawọn afiniṣowo.

Kọmiṣanna ọlọpaa, ni Kwara, CP Victor Olaiya, lo ṣafihan wọn fawọn oniroyin l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii. O ṣalaye pe baba ọmọbinrin ọhun to n jẹ  Yusuf Taofeek, lo mu ẹsun lọ si agọ ọlọpaa, ẹka ti ilu Ọffa, pe wọn ran Rianat ko lọọ ra kulikuli ti wọn yoo fi mu gaari wa ninu, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2021, ṣugbọn to dawati, eyi lo mu ki awọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun lẹkun-un-rẹrẹ.

O  tẹsiwaju pe iwadii ti wọn ṣe lo mu ki ọlọpaa mu Fẹmi Adeniji, to si jẹwọ pe loootọ, oun loun pa oloogbe naa lati fi ṣoogun owo, toun si ti ta apa rẹ kan fun ọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Shittu Abdulmalik Wale, to n gbe ni agboole Imam, niluu Offa, ni ẹgbẹrun lọna ogun Naira. Eyi lo mu ki awọn agbofinro fi panpẹ ofin gbe awọn mejeeji.

Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Kwara, CP Victor Olaiya, ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa, o ni lẹyin iwadii lawọn yoo taari wọn lọ sile-ẹjọ.

 

Leave a Reply