Ajalu buruku lagbo tiata! Sisi Quadri ku lojiji

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Agbọ-sọgba-nu ni iku ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa tawọn eeyan fẹran daadaa nni, Tọlani Qadri Oyebamiji, ti gbogbo eeyan mọ si Sisi Quadri.

Bo tilẹ jẹ pe Sisi Kadiri lawọn eeyan mọ ọn si nitori bo ṣe maa n ṣe bii obinrin, ati bo ṣẹ maa n ṣẹ ẹẹkẹ eebu bii obinrin, orukọ rẹ gan-an ni Tọlani Qadri Oyebamiji. Ere ‘Ṣeniyan Ṣẹranko’ nibi to ti ṣe ẹẹkẹ eebu daadaa lo gbe e saye, bo tilẹ jẹpe o ti kopa daadaa ninu ere Oloogbe Ajilẹyẹ.

Ojiji ni iku oṣere tawọn eeyan maa n lo ninu ere daadaa, paapaa eyi to ba ti jẹ mọ awada naa gba ori ayelujara kan. Ohun to n ṣẹ awọn eeyan ni kayeefi lori iku rẹ ni pe ko sẹni to gbọ pe o n ṣaisan tabi pwe nnkan kan n ṣe ẹ. Eyi lo fa a ti ọpọ eeyan ko fi gbagbọ pe oṣere naa ti tẹri-gbaṣọ.

Ọmọ bibi ilu Iwo, nipinlẹ Ọṣun, ni. Ọdun 1979 ni wọn bi i. Bi ọrọ ṣe da lẹnu rẹ, to si maa n ṣe bii obinrin lo sọ ọ di gbajumọ laarin awọn oṣere ẹgbẹ ẹ

Ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2020, lo ṣile to kọ si ilu Iwo, nibi to n gbe. Iṣẹ telọ lo yan laayo laaarọ ọjọ rẹ ko too di pe o darapọ mọ awọn oṣere tiata.

Ọkan-o-jọkan ere ni oṣere naa ti kopa. O ti ṣere lẹyin Oloogbe Ajilẹyẹ. Bakan naa ni oun ati Funmi Awẹlẹwa toun naa jẹ oṣere ṣere kan ti wọn pe ni ‘Eebudọla’, eyi ti awọn eeyan tẹwọ gba daadaa. Tọkọ-tiyawo ni wọn jọ ṣe ninu ere naa.

Lọdun to kọja ni oṣere yii rin irinajo lọ si ilẹ mimọ Mecca.

Ọmọ meji, Ọlamilekan Oyebamiji ati Ọlamide Oyebamiji, pẹlu iyawo kan ni oṣere naa fi saye lọ.

Ọjọ to ku yii ni wọn bẹrẹ si i ṣe afihan ere ọlọsọọsẹ kan ti kunle Afọlayan kọ, eyi to pe ni ‘Anikulapo’, nibi ti ọmọkunrin naa ti kopa to jọju. Ọpọ awọn ti wọn si gbọ nipa iku rẹ ni wọn n pariwo pe aọn ṣẹṣẹ wo o tan ninu ere naa ni

 

 

Leave a Reply