Eyi laṣiiri iku to pa Sisi Quadri

Jọkẹ Amọri

Bo tilẹ jẹ pe oṣerekunrin ti gbogbo eeyan fẹran daadaa nni, Tọlani Qadri Oyebamiji, ti gbogbo eeyan mọ si Sisi Quadri ti ku, wọn si ti sinku rẹ nilana ẹsin Musulumi, kinni kan to daju ni pe ọpọ eeyan ni ko ni i gbagbe rẹ nitori ẹrin to maa n mu pa ẹẹkẹ awọn ololufẹ rẹ nigbakigba to ba n ṣere ati bi oṣere naa ṣe ni ẹbun ka buuyan, ka fi tọhun we nnkan, ti ko si ni i fikan pe meji to ba n ṣe bẹẹ. Ti yoo maa ṣeju peu peu, ti yoo ma ṣe bii obinrin bi kinni naa ba ti wọ ọ lara.

Ni bayii, ALAROYE ti ṣewadii nipa ohun to ṣokunfa iku ojiji to pa oṣere yii, a si le fi gbogbo ẹnu sọ fun yin pe ki i ṣe aisan kindinrin ni oṣere lẹgẹlẹgẹ naa ni ti iku fi pa a.

Ọkan ninu awọn mọlẹbi oṣere naa to sun mọ ọn daadaa torukọ rẹ n jẹ Ahmed, ṣalaye pe ahesọ patapata ni ohun ti awọn eeyan n gbe kiri nipa iku oṣere ọmọ bibi ilu Iwo, nipinlẹ Ọṣun ọhun. O ni ohunkohun ti ẹnikẹni ba sọ yatọ si eyi ti oun sọ yii, ahesọ gbaa ni, Quadri ko ni aisan kindinrin kankan. Ọmọkunrin yii ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin ni oṣere naa wa loko ere, ti gbogbo awọn to wa nibẹ si ri i pe oju ọkunrin naa ko ṣee wo, ara rẹ ko fi bẹẹ le. O n rẹ ẹ. Wọn si kọkọ tọju rẹ ni otẹẹli to de si loko ere ọhun ko too di pe o gba ọsibitu lọ lati tọju ara rẹ.

Ninu esi ayẹwo ti wọn ṣe fun un lọsibitu ni wọn ti ri i pe aisan iba taifọọdu lo n ba oṣere yii finra. Oju-ẹsẹ naa ni wọn ti bẹrẹ itọju fun un, to si wa ni ọsibitu naa fun odidi ọsẹ kan ati ọjọ diẹ, nibi to ti gba itọju. Lẹyin ti ara rẹ mokun ni awọn dokita ni ko maa lọ sile.

Ṣugbọn ko ju ọjọ diẹ lẹyin asiko to kuro ni ọsibitu ti kinni ọhun tun fi gba a mu, o si waa le ju ti akọkọ lọ. Wọn ko wo oṣere yii niran ti wọn fi sare gbe e lọ si ọsibitu aladaani kan, latibẹ ni wọn ti gbe e lọ si ọsibitu ẹkọṣẹ iṣegun ti ileewe giga Yunifasiti LAUTECH, to wa niluu Ogbomọṣọ.

Esuke ni wọn sọ pe o n ṣe oṣere to kopa ninu fiimu kan ti Funmi Awẹlẹwa ṣe ti wọn n pe ni ‘Eebudọla’ yii. Esuke naa pọ diẹ gẹgẹ bi Ahmed ṣe sọ. O ni eyi lo ba ọpọ eeyan lẹru nitori bi alaaarẹ ba wa nidubulẹ aisan, ti ko ba ti mu ọrọ esuke dani, ọkan maa n balẹ pe yoo gbadun. Ṣugbọn to ba ti di ọrọ oni esuke, bii marun-un ninu ọgọrun-un alaisan ti eleyii ba n ṣe ni ireti wa pe o le gbadun, ti ko si ni i ja si iku.

Ọkunrin naa ni gbogbo agbara ni awọn dokita ṣa lati ri i pe wọn dawọ esuke to n ṣe oṣere apani-lẹrin-in ọhun duro, ṣugbọn ko ṣee ṣe. Lẹnu eleyii ni ọlọjọ de ba oṣere ọmọ bibi ilu Iwo naa, to si ki aye pe o digbooṣẹ.

Titi di ba a ṣe n sọ yii lo nira gidigidi fun ọpọ eeyan lati gbagbọ pe oṣere naa ti jade laye. Ohun to mu kọrọ naa si jẹ iyanu ati kayeefi fun ọpọ eeyan ni pe ọjọ to ku yii ni wọn bẹrẹ afihan ere kan ti Kunle Afọlayan kọ to ti kopa oku to n yọ siiyan. Ariwo ti ọpọ si n pa ni pe, ‘mo ṣeṣẹ wo ọkunrin naa tan ninu ere Kunle Afọlayan ni’ Awọn mi-in si n sọ pe abi ipa oku to ko ninu ere naa, to si jade lọjọ to ku fi han pe o ti mọ pe oun maa ku ni.

Ṣa o, aisan lo ṣee wo, ko sẹni to ri tọlọjọ ṣe, Sisi Quadri ti gbe gbogbo ọgbọn imọ ati awọn ede to maa n pe to fi maa n pa awọn ololufẹ ẹ lẹrin-in lọ sọrun aṣante.

Leave a Reply