O ma ṣe o, Sisi Quadri n mura ilu oyinbo lọwọ niku mu un lọ

 

 

Ọrẹoluwa Adedeji

Yoo ṣoro ki iku oṣere adẹrin-in-poṣonu nni, Tọlani Qadri Oyebamiji, ti gbogbo eeyan mọ si Sisi Quadri, too tete tan lara mọlẹbi atawọn ololufẹ rẹ. Eyi to si n dun wọn ju ni iroyin to jade pe wọn ti fun oṣere naa ni fisa lati lọ si orileede Amẹrika, bẹẹ ni oun ati promota rẹ ti mu ọjọ ti irinajo naa yoo jẹ, ti oun paapaa si ti n palẹmọ, ko too di pe iku ṣi i lọwọ iṣẹ lojiji, ti ko si jẹ ki erongba rẹ lati tẹsiwaju lọ siluu oyinbo, ko le lọọ foju rinju pẹlu awọn ololufẹ rẹ wa si imuṣẹ.

Pẹlu ibanujẹ ni ọkunrin promoter naa ti orukọ rẹ n jẹ Ọlawale B. to ni ileeṣẹ to n gbe awọn oṣere larugẹ ti wọn n pe ni ‘Fathia Entertainment’ fi kọ ọ sori ayelujara pe, ‘‘O jẹ ibanujẹ ọkan fun mi lati gbọ nipa iku Sisi Quadri. Wọn ti fun un ni fisa ti yoo fi rinrin-ajo lọ si orileede Amẹrika. A ti mu ọjọ ti irinajo naa maa waye. Ṣugbọn ta ni wa lati ba Ọlọrun wijọ’’.

Irọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹta, ọdun yii, ti oṣere naa ti dakẹ si ọsibitu LAUTECH, niluu Ogbomọṣọ, ni wọn ti gbe oku rẹ kuro nibẹ wa s’Iwoo, ti ṣe ilu abinibi rẹ. Mọto bọọsi funfun gbokuu-gbalaaye kan ti wọn kọ orukọ ileewe giga Fasiti Ladoke Akintọla si ni wọn fi gbe oku rẹ wọ ilu Iwo, nipinlẹ Ọṣun. Bẹẹ ni awọn mọto mi-in tẹle e, ninu eyi ti awọn to mọ oṣere naa daadaa sọ pe ọkan ninu awọn mọto to ṣẹṣẹ ra wa ninu ẹ, aṣe ko ni i gun mọto naa to maa fi ku.

Bii omi lero n wọ tẹle ambulansi to gbe oku ilu-mọ-ọn-ka oṣere naa. Bẹẹ ni awọn ọlọkada ilu naa ni ki lo ṣubu tẹ awọn. Niṣe ni gbogbo wọn to lọ bẹẹrẹ bẹ, tawọn eeyan lọkunrin, lobinrin, ọmọde atagba, paapaa si n sare tẹle oku naa bi wọn ṣe n gbe e lọ si mọṣuari ijọba to wa niluu Iwo. Owe Yoruba to maa n sọ pe ka ku lọmọde ko yẹ ni, o san ju ka dagba dagba ka ma ni adiyẹ irana yoo si wa sọkan eeyan pẹlu omilẹgbẹ ero to tẹle oku ọmọkunrin naa.

Ariwo, ‘Qadiri ti ku ooo, ogo ilu Iwo ti ku’… lo gba ẹnu awọn kan. Ọkunrin kan bara jẹ gidigidi ninu fidio ọhun, bẹẹ lo si n pariwo pe, ‘’Ọlọrun o, ta a ti ro pe iwọ lo maa fa awa to ku goke, iru iku wo leleyii’’ Bakan naa ni ẹlomi-in ni, ‘Inu wa maa n dun ba a ba ti ri ọ ni, nitori o n gbe orukọ ilu Iwo ga, ogo Iwo lo jẹ, ko yẹ ki iku ti i mu ọ lọ laarin wa bayii’’.

Niṣe ni ariwo ẹkun sọ nigba ti wọn gbe okun oṣere naa jade ninu ambulansi, ti wọn si ṣe e lọjọ si mọṣuari naa lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹta yii.

Leave a Reply