Awọn eeyan bara jẹ gidigidi nibi isinku Sisi Quadri, eyi lohun ti wọn sọ nipa rẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ka ku lọmọde ko yẹ ni, o san ju ka dagba ka ma ni adiyẹ irana. Owe yii lo ṣe rẹgi pẹlu oṣere aderin-poṣonu nni, Tọlani Qadri Oyebamiji, ti gbogbo eeyan mọ si Sisi Quadri. Ko jọ pe iye ero to jade wa si agboole wọn lọjọ isinku rẹ yii ti i kora wọn jọ pọ soju kan bayii ri. Bii omi ni awọn eeyan n wọ lọ sile oṣere yii, awọn mi-in si n sọ pe awọn fẹẹ lọọ foju awọn ri i boya awọn eeyan n parọ iku mọ ọn ni.

Niṣe ni ẹkun n pera wọn ranṣẹ, ko si si ẹni to le rẹ ara wọn lẹkun ninu awọn mọlẹbi, ọmọ ilu atawọn ololufẹ oṣere yii. Onikaluku kan n wa ẹkun mu bii gaari ni, ko si sẹni to ṣe ẹni kan ni pẹlẹ.

Ẹsẹ ko gbero lagboole Agbowo, niluu Iwo, nipinlẹ Ọṣun, laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keji, osu Kẹta yii, nibi isinku ọkunrin oṣere tiata ilẹ wa nni, Quadri Oyebamiji Tọlani, ti gbogbo eeyan mọ si Sisi Quadri.

Ọsẹ kan sẹyin la gbọ pe Oyebamiji, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Sisi Quadri, deede ṣubu lulẹ loko ere tiata kan, wọn si tọju rẹ, bẹẹ lo pada sile rẹ to kọ siluu Iwo.

Lẹyin to gba itọju aisan iba (malaria) ni ọsibitu kan to wa lagbegbe Ori-Eérú, niluu Iwo, lo di pe o bẹrẹ esuke (hiccups) lọjọ marun-un sẹyin.

Nigba ti esuke yii ko dawọ duro ni dokita sọ fun un pe ki wọn lọọ ṣayẹwo rẹ ni LAUTECH, Ogbomọṣọ. Aarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹta, ni aburo rẹ kan gbe e lọ si Ogbomọṣọ, koda, a gbọ pe awada ni wọn ṣe debẹ.

Wọn ni miliọnu kan Naira lo tiransifaa lati inu akaunti rẹ si ti aburo rẹ pe awọn le fẹẹ nilo owo tawọn ba de ọsibitu. Bakan naa lo sọ pe aọn lo ko ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira to wa ninu mọto rẹ fun nigba ti awọn n lọ.

O ni ki i ṣe pe aisan naa fi bẹẹ da a gbalẹ rara, nitori nigba ti awọn n lọ ti ọlọpaa da awn duro ti wọn beere owo lọwọ rẹ, niṣe lo ba wọn ṣawada pe ki wọn lọọ gba a lọwọ Sanwoolu.

Gẹgẹ bi awọn ti wọn jọ lọ si ọsibitu ṣe ṣalaye, awọn dokita ko wo o niran rara, kia ni wọn da a lohun, ṣugbọn gbogbo nnkan yiwọ nigba to fi maa di aago mẹta ọsan, Sisi Quadri dagbere faye laago mẹta aabọ ọsan.

Alẹ ọjọ Ẹti naa ni wọn gbe oku rẹ de si General Hospital, to wa niluu Iwo, bi ilẹ ọjọ Satide si ti mọ ni wọn ti bẹrẹ si i gbẹ saare ti wọn yoo sin in si niwaju ile rẹ.

Latari bi ogunlọgọ awọn araalu, ojulumọ atawọn ẹgbẹ oṣere tiata ṣe ya bo ile rẹ, awọn mọlẹbi atawọn aafa fẹnu ko pe ki wọn kọkọ kirun si oku rẹ lara lori fiidi (field) Central Mosque, kan to wa nitosi ile rẹ.

Nnkan bii aago mọkanla aabọ aarọ ni wọn gbe oku rẹ de, ẹsẹ ko si gba ero nibẹ. Pẹlu agbara ni wọn fi raaye gbe oku rẹ silẹ fun adura, bi wọn si ti ṣetan ni wọn gbe e lọọ sin nilee rẹ.

Lẹyin naa ni awọn eeyan wọ lọ si ile baba rẹ to wa ni Agọ Adúmádèé, niluu Iwo, lati ba baba naa kẹdun.

Yatọ si pe Sisi Quadri jẹ oṣere tiata, aranṣọ tun ni, o si ti kọ awọn ọmọọṣẹ to to mọkanlelọgbọn niṣẹ naa, koda, a gbọ pe o ṣe firidọọmu fun ọmọọṣẹ rẹ kan lọjọ Satide to kọja.

Leave a Reply