Ọwọ ba Yusuf at’ọrẹ ẹ, awọn akẹkọọ-binrin ni wọn maa n digun ja lole lositẹẹli KWASU 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan ni tolohun, owe yii lo ṣe rẹgi pẹlu awọn ọkunrin meji kan, Abdulkareem Yusuf, ẹni ọgbọn ọdun, ati Mubaraq Abdurahamọn tọwọ ọlọpaa tẹ lẹyin tawọn mejeeji lọọ digun ja awọn akẹkọọ-binrin lole ni ile ti wọn n gbe ni Fasiti KWASU, ilu Màlété, nipinlẹ Kwara.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejila, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, ni awọn

akẹkọọ-binrin meji kan, Maryam Brimah ati Brimah Maymunah, mu ẹsun lọ sileeṣẹ ọlọpaa pe lasiko tawọn n sun lọwọ ni ositẹẹli awọn to wa ni Ajibson, ni awọn adigunjale kan ka awọn mọle pẹlu ibọn ati ohun ija oloro miiran, ti wọn si dunkoko lati gba ẹmi awọn. Wọn gba foonu, wọn tun ji owo wọn lọ.

Kọmisanna ọlọpaa ni Kwara, CP Victor Olaiya, fidi ẹ mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Keji, to kọja yii, pe lẹyin tawọn gba ipe pajawiri pe  awọn adigunjale bii mẹta ṣọṣẹ fawọn akẹkọọ-binrin nile ti wọn n gbe, loju-ẹsẹ lawọn ti ṣeto ki ikọ ọlọpaa lọọ koju awọn apamọlẹkun-jaye ẹda naa, ki wọn si wa wọn lawaari.

O ni, ọwọ pada tẹ meji ninu awọn afurasi adigunjale yii, iyẹn Abdulkareem Yusuf, ati Mubaraq, to n gbe ni agbegbe Ìta-Àmọ́, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, ti wọn si ri awọn ẹru ti wọn ji gbe bii: foonu Samsung Galaxy, atawọn ohun miiran gba lọwọ rẹ, tawọn ọlọpaa si n wa awọn to sa lọ bayii.

Ọlaiya ni lẹka awọn ọtẹlẹmuyẹ ni wọn wa bayii, nibi ti wọn ti n ran wọn lọwọ ninu iwadii, ti iwadii ba pari ni yoo foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply