Ọwọ tẹ ọga ṣọja yii, oun ati tọkọ-tiyawo kan lo n tẹ ayederu owo

Adewale Adeoye

Ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe ‘Zone 2 Command’, niluu Eko, ni ọga ṣọja kan, Ọgagun Ilelabayọ Johnson, ẹni ọdun marundinlogoji atawọn mẹta kan ti wọn fẹsun kan pe wọn n tẹ ayederu owo Naira ilẹ wa ati Cefas tilẹ Cameroon, wa bayii.

Awọn mẹta ọhun ti wọn wa lahaamọ ọlọpaa pẹlu Ọgagun Ilelabayọ Johnson yii ni tọkọ-taya meji kan, Ọgbẹni Oludare, ẹni aadọta ọdun, iyawo rẹ, Abilekọ Oluwayẹmisi ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta ati Ọgbẹni Adeniyi Quadri, ẹni ọdun mejilelọgọta.

ALAROYE gbọ pe lọjọ kẹta, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni ọwọ awọn ọlọpaa tẹ Ọgbẹni Quadri, to n ba wọn tẹ ayederu owo Naira ati Cefas nile rẹ. Awọn Hausa to n ṣẹ owo ilẹ okeere ni wọn maa n ko ayederu owo orileede Cameroon ti wọn ba tẹ fun, nigba ti Abilekọ Yẹmisi to jẹ oniṣowo P.O.S lagbegbe naa maa n fi ayederu Naira ọhun sanwo fawọn araalu.

Oga agba ọlọpaa ẹka ti Zone 2, A.I.G Durosanmi, to ṣafihan awọn ọdaran ọhun fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹta, ọdun yii, niluu Eko, sọ pe awọn owuyẹ kan ti wọn mọ nipa iṣẹ laabi ti Quadri maa n ṣe lo waa fọrọ rẹ to awọn leti, ti D.S.P Adeyẹmi Akeem si ṣaaju ikọ ọlọpaa kan to lọọ fọwọ ofin mu un. Wọn ba miliọnu lọna ọọdunrun Cefas ati miliọnu mẹsan-an Naira nile rẹ lasiko ti wọn mu un.

Loju-ẹsẹ lo jẹwọ pe o ti to nnkan bii ọdun mẹta sẹyin toun ti wa ninu iṣẹ laabi ọhun. To si darukọ gbogbo awọn ẹlẹgbẹ rẹ ti wọn jọ n ṣiṣẹ buruku ọhun fawọn ọlọpaa. Quadri yii kan naa lo mu awọn ọlọpaa dele awọn Oludare Yẹmisi ati ọkọ rẹ, Ọgbẹni Oludare Ọlamilekan. Awọn tọkọ-taya yii ni wọn tun ṣofofo pe Ọgagun Ilelabayọ Johnson to ti fẹyinti ninu iṣẹ ologun ni igi lẹyin ọgba awọn. Wọn lọọ fọwọ ofin mu oun naa nile rẹ to wa l’Ojule kẹta, Ilelabayọ Close, lagbegbe Ajasa, niluu Eko.

Nigba tawọn ọlọpaa yẹ ile Ilelabayọ wo, wọn ba awọn ayederu owo Naira ilẹ wa ati Cefas tilẹ okeere to pọ daadaa nibẹ.

Ọdọ awọn ọlọpaa ọhun ni kaluku wọn ti jẹwọ ipa ti wọn n ko ninu iṣẹ laabi ọhun.

Quadri ni Oludare lo pe oun siṣẹ naa ni nnkan bii ọdun marun-un sẹyin, ati pe ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira ni wọn maa n foun lati ba wọn tẹ miliọnu Naira kan, ayederu miliọnu mẹsan-an Naira loun ti ba wọn tẹ ko too di pe ọwọ tẹ oun bayii.

Ni ti Oludare, o jẹwọ pe loootọ oun loun ni awọn ayederu owo Naira ilẹ wa ati ti Cefas tilẹ okeere ti wọn ba nile oun yii, awọn Hausa loun maa n ko owo ilẹ okeere ọhun fun, nigba ti iyawo oun, Abilekọ Yẹmisi to jẹ oniṣowo P.O.S maa n na awọn ayederu owo Naira ọhun fawọn araalu.

Awọn ọlọpaa ti lawọn maa too bẹrẹ iwadii nipa ọrọ awọn ọdaran ọhun, tawọn si maa foju gbogbo wọn bale-ẹjọ lori ohun ti wọn ṣe.

 

Leave a Reply