Awọn tọọgi da mọto tirela to n ko ounjẹ lona, gbogbo ẹru inu rẹ ni wọn ji ko pata

Adewale Adeoye

Ni nnkan bii aago mẹta kọja iṣẹju mẹẹẹdogun, Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, lawọn janduku kan ti wọn pọ niye da mọto tirela kan to n gbe oriṣiiriṣii ohun ti ẹnu n jẹ lọna lagbegbe Dogarawa, lojuna marosẹ Zaria si Kano, ti wọn si ji gbogbo irẹsi, Spaghetti atawọn oriṣiiriṣii nnkan ti ẹnu n jẹ to wa ninu mọto ọhun ko lọ rau.

Arọ ti ko le rin paapaa ni ki wọn gbe oun debẹ, nigba tawọn janduku ọhun n gbe paali awọn ounjẹ ọhun ti kaluku wọn si n du pe kawọn ko eyi to maa to awọn lati jẹ fun ọjọ bii meloo kan.

ALAROYE gbọ pe ilu Abuja, ti i ṣe olu ilẹ wa ni dẹrẹba mọto tirela ọhun n gbe awọn ọja naa lọ, ṣugbọn nigba ti asiko lati kirun to fun un lo ba paaki mọto rẹ sẹgbẹẹ kan, to si ṣe aluwala, lo ba n kirun lọ. Bawọn ọmọ ganfe ti ebi n pa ti wọn n rin kaakiri aarin ilu lati wa ounjẹ ṣe ri tirela naa ni wọn ti sare kora wọn jọ lati ṣiṣẹ laabi ọhun.

Loju-ẹsẹ ni wọn ti ko igi dina, ti wọn si kina bọ ọ, eyi ko si fun awọn ọlọpaa tabi awọn ọkọ mi-in laaye lati kọja sibi ti wọn wa. Gbogbo ẹru inu mọto ọhun ni wọn ji ko pata.

Ọkan lara awọn olugbe agbegbe ibi ti iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ ṣalaye pe oun ko ti ri ibi ti ebi ti pa awọn araalu to bayii ri, nitori pe ṣe ni wọn n kigbe pe ebi ati iya lo jẹ kawọn lọọ ṣe iru nnkan yii.

Onitohun ni, ‘Mi o ri iru nnkan bayii ri latigba ti mo ti daye, pe kawọn araalu atawọn janduku maa ji ọja inu mọto ko, afi bii igba ti wọn fi igbalẹ gba gbogbo inu mọto ọhun ni, ṣe ni wọn ji gbogbo iresi, spaghetti atawọn oriṣiiriṣii nnkan ti ẹnu n jẹ to wa ninu tirela ọhun ko lọ, bẹẹ kẹ, irun ni dẹrẹba ọkọ ọhun n ki ko too di pe wọn kogun ja a. Ṣe ko ti waa daran bayii, gbese nla gbaa ni wọn da dẹrẹba ọkọ ọhun ati oniṣowo to ni ọja naa’’.

Awọn ọlọpaa ti wọn pe lori foonu debẹ lẹyin tawọn janduku ọhun ti lọ tan, ti wọn si pada fọwọ ofin gba awọn araalu marun-un kan mu lori iṣẹlẹ ọhun.

 

Leave a Reply