Eyi nidi ti Wasiu Ayinde ko fi ni i ṣayẹyẹ ọjọọbi rẹ lọdun yii

Adewale Adeoye

Gbajumọ olorin fuji nni, Wasiu Ayinde Marshal, ẹni tawọn eeyan mọ si ‘K1 De Ultimate’, ti loun ko ni i ṣayẹyẹ ọjọọbi oun lọdun yii, nitori bi ilu ṣe le koko bii oju ẹja fọpọ awọn eeyan ilẹ yii.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹta, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, lo yẹ ki Ọba orin pe apejẹ pataki pe kawọn ololufẹ rẹ gbogbo nilẹ yii ati l’Oke-Okun waa ba a ṣajọyọ ọjọọbi yii gẹgẹ bo ṣe maa n ṣe lọdọọdun, ṣugbọn o ti fagi le e bayii pe oun ko ni i ko ilu sita tabi ṣe ohun Kankan, nitori  ebi n pa araalu gidi lasiko yii.

Ṣa o, Kwam1 rọ ẹbi, atawọn ọrẹ rẹ gbogbo ti wọn lowo lọwọ daadaa pe ki wọn lo akoko ayajọ ọjọọbi oun yii lati fi ṣeranlọwọ fawọn mẹkunu ti ẹbi n pa lorileede yii.

Atẹjade kan ti Oluaye gẹgẹ bi awọn kan ṣe n pe e fi sita ni Tọsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii lọ bayii pe, ‘Mo fi ọpẹ ati iyin fun Ọlọrun Ọba pe lọjọ kẹta, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni ma a pe ẹni ọdun mẹtadinlaaadọrin lorilẹ aye. Ọjọ ayọ ati idunu ni asiko ti mo maa n ṣe ọjọọbi mi maa n jẹ fun mi nigba gbogbo, leyii tawọn ẹbi, ara, ọrẹ ati ojulumọ nilẹ yii ati l’Oke-Okun maa n waa ba mi yọ nigba gbogbo, ṣugbọn bi nnkan ṣe ti ri lorileede wa lasiko yii, ilu le gidi, agbara kaka lawọn eeyan fi n rọwọ ki sẹnu. Nnkan ko lọọ deede fọpọ ẹbi, iya ati iṣẹ wa laarin ilu, eyi atawọn ohun kọọkan to n ṣẹlẹ lorileede yii ni ko ni i le jẹ ki n ṣẹyẹ ọjọọbi mi lọdun yii gẹgẹ bii iṣe mi.

‘‘Loootọ mọ gba pe ọpọ ọmọ orileede yii lo n la oke iṣoro kọja, ṣugbọn eyi ko le maa lo bẹẹ titi, laipẹ yii, gbogbo nnkan maa too yipada si daadaa.

Ijọba n gbiyanju gidi lati ṣakoso ijọba Naijiria lọna ti yoo gba rọ gbogbo araalu lọrun, laipẹ, iyatọ maa waye.

Fun idi eyi, mo n fi asiko yii rọ awọn ololufẹ mi gbogbo nilẹ yii ati l’Oke-Okun pe eyi tẹ ẹ maa fi waa ki mi lati ba mi ṣajọyọ ọjọọbi mi yii, ẹ lo ohunkohun ti ẹ ba ni lati fi ṣeranlọwọ gidi fawọn mẹkunu, ki inu awọn naa dun lasiko ajọyọ ọjọọbi mi yii. Mo gbadura pe Ọlọrun Ọba aa fọpọ rọpo fun yin bẹẹ ba le ṣe bẹẹ.

 

Leave a Reply