O ma ṣe o! Awọn afiniṣowo ti pa awọn obinrin mẹta tẹ ẹ n wo yii ṣoogun l’Ogun

Faith Adebọla

Awọn obinrin arẹwa apọnbeporẹ tẹ ẹ n woju wọn ninu fọto yii ko si laye mọ ba a ṣẹ n kọ iroyin yii, gbogbo wọn ti ku. Ohun to dun ni nibẹ ni pe iku ojiji ni wọn ku, wọn ko fọwọ rọri ku rara. Nibi to buru de,  o ṣee ṣe kawọn mọlẹbi wọn ṣi maa daamu wa wọn kiri, tori ko sẹni to gbọ nipa bi wọn ṣe ku ati ibi ti wọn sinku wọn si. Awọn afeeyan-ṣetutu ọla ni wọn ko si lọwọ, awọn ni wọn pa wọn, ti wọn si lo ẹya-ara wọn fi ṣoogun owo.

Ṣe ile iku laa ti i jẹwọ arun, iwadii ijinlẹ ti awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣe lori ọrọ awọn afeeyan-ṣetutu ti wọn jẹwọ pe awọn ti pa obinrin mẹwaa niluu Atan, nijọba ibilẹ Ado-Odo/Ọta, nipinlẹ Ogun, lo taṣiiri awọn obinrin ti wọn kagbako iku ojiji wọnyi, ti wọn fi ri fọto awọn diẹ lara wọn.

Ninu alaye ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Ọmọlọla Odutọla, ṣe f’ALAROYE ninu atẹjade rẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keji, oṣu Kẹta yii, o ni lẹyin ti ọwọ ti ba Azeez Ọlamide Adebayọ, afurasi ọdaran ẹni ọdun marundinlogoji, to gbowọ ninu fifi ẹtan mu awọn obinrin naa wa si ojubọ ibi ti wọn ti n yin wọn lọrun pa, lawọn ọlọpaa bẹrẹ si i yẹ gbogbo awọn ohun to wa lori foonu igbalode andirọidi rẹ wo. Wọn lọ sori ikanni My Chat, nibi to loun ti n pade awọn obinrin to n fi ifẹ tan loriṣiiriṣii, wọn si ri ọgọọrọ ọrọ ifẹ ati ẹtan ti oun atawọn obinrin naa fi n ṣọwọ sira wọn.

Lori foonu ọhun ni wọn ti ri apoowe kan, nibi to maa n tọju fotọ awọn obinrin loriṣiiriṣii si. Awọn ọlọpaa bi i leere bi awọn fọto naa ṣe jẹ. Ṣe ko kuku si ifun kan ninu oromọdiẹ ti awodi ko mọ, loju-ẹsẹ ni Azeez ti n ka boroboro, bi wọn ṣe n tọka si awọn fọto kọọkan lo n jẹwọ orukọ wọn, o si n sọ eyi ti wọn ti pa danu lara wọn.

O pe orukọ ọkan ni Ezeh Chizom, o lawọn ti lo o, ọkan to tun jẹ Enny, o loun ko mọ boya Ẹniọla lorukọ ẹ gan-an ko too sọ ọ di Enny, amọ awọn sa ti pa a, fọto kẹta lo loun ko ranti orukọ ẹ, wọn ti pa iyẹn naa.

Ẹ oo ranti pe ṣaaju ni Azeez yii ti jẹwọ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ALAROYE l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Keji to kọja yii, lẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni GRA Ibara, l’Abẹokuta, pe obinrin meje lawọn ti pa latigba toun ti n fẹtan mu wọn lori ikanni MyChat. Lara wọn ni Adijat Sulaimọn ati Sarah Abọsẹde Ọlanrewaju, ti wọn pa laarin ọjọ meji sira wọn, ninu oṣu Kin-in-ni, ọdun yii.

Ẹ tun maa ranti pe baagi obinrin mẹwaa ọtọọtọ ni wọn ba nile Moses Aruwaji, ọkunrin toun ati iyawo rẹ, Maria Aruwaji, jọ n ṣiṣẹ afeeyan-ṣetutu pẹlu Azeez. Wọn ni palọ rẹ ni Azeez ti n fun awọn obinrin yii lọrun pa, ti Maria si n ba wọn di ẹsẹ ẹni ti wọn fẹẹ pa mu, oun naa lo si maa n nu ẹjẹ awọn oloogbe ọhun lẹyin ti wọn ba ti kun wọn bii ẹran, ti wọn si ti yọ awọn ẹya ara ti wọn fẹẹ lo tan. Ori, ọwọ, ẹsẹ, ọyan ati abẹ lawọn ẹya ara ti wọn lawọn maa n ta fawọn to fẹẹ fi i ṣoogun owo.

Alukoro ti parọwa sawọn araalu lati ṣeranwọ fawọn agbofinro, ki ẹnikẹni teeyan rẹ ba sọnu tara ṣaṣa lọ solu ileeṣẹ ọlọpaa Ogun, pẹlu ẹri to daju. Bakan naa ni wọn lawọn ṣi n wa afurasi ọdaran meji kan, Ṣẹgun ati eyi ti wọn n pe ni Aafaa Ariwo, ti wọn fẹsun kan pe wọn jọọ n ṣiṣẹ ọdaju buruku yii ni.

Leave a Reply