Atundi ibo sẹnetọ: Tokunbọ Abiru lo jawe olubori l’Ekoo

Jide Alabi

Ajọ eleto idibo, INEC, ti kede Tokunbọ Abiru, ẹni to n dije dupo aṣofin agba lati ṣoju agbegbe Ila-Oorun ipinlẹ Eko niluu Abuja lo jawe olubori l’Ekoo.

Gẹgẹ bi ajọ INEC ṣe kede ẹ, ibo to fẹẹ to ẹgbẹrun lọna aadọrun-un (89,204) ni ọkunrin yii na alatako rẹ, nigba ti Babatunde Gbadamosi to tẹle e ninu idije ọhun ni ibo to le diẹ ni ẹgbẹrun mọkanla (11,257).

Ni gbogbo ijọba ibilẹ marun-un to wa ni Ila-Oorun ipinlẹ Eko ti Tokunbọ Abiru fẹẹ lọọ ṣoju fun niluu Abuja, oun lo jawe olubori.

 

Leave a Reply