‘Awa ko fara mọ aarẹ ati igbakeji ẹlẹsin kan naa’

Faith Adebọla

 Lọgbọlọgbọ gidi lo n lọ lọwọ ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, ẹkọ ko si ti i ṣoju mimu fun ẹgbẹ naa lori ọrọ yiyan aarẹ ati igbakeji rẹ ti wọn jọ jẹ ẹlẹsin Musulumi. Ogunlọgọ eeyan lo tun ṣewọde ta ko igbesẹ naa l’Abuja, wọn lawọn o si ni i yee ṣewọde, afi ti ẹgbẹ APC ba yii ipinnu wọn pada.

Ọjọruu, Wẹsidee, ogunjọ, oṣu Keje yii, ni iwọde naa waye, o si ṣe kongẹ asiko ti Oloye Bọla Ahmed Tinubu atawọn agbaagba ẹgbẹ APC ṣafihan gomina ipinlẹ Borno ana, Sẹnetọ Kashim Shettima, gẹgẹ bii oludije funpo igbakeji aarẹ labẹ asia ẹgbẹ naa lọdun 2023, eyi ti wọn ṣayẹyẹ rẹ ni gbọngan apero Shehu Musa Yar’Adua Centre, niluu Abuja.

Oriṣiiriṣii akọle lawọn oluwọde ti wọn pe orukọ ẹgbẹ wọn ni APC Hausa-Fulani Youth Forum, gbe dani. Lara awọn akọle naa ni: “Ẹ yọ Shettima o, ẹ jẹ kawọn ọmọọya wa ẹlẹsin Kirisitẹni bọ sipo naa.” “Iwa ojooro lorileede wa leyi,” “A n kigbe pe kẹ ẹ ṣedajọ ododo,” ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ọkọ akero gbọgbọrọ mẹfa atawọn ọkọ ayọkẹlẹ rẹpẹtẹ lo gbe awọn ero naa wa.

Ẹni to lewaju wọn, Abdullahi Bilai Mohammdu, sọ pe iwa aiṣedajọ ododo ni APC hu pẹlu bi wọn ṣe gba ki oludije funpo aarẹ ati igbakeji ẹ jẹ ẹlẹsin Musulumi kan naa, ti wọn o tiẹ ri tawọn ẹlẹsin Kirisitẹni ro rara, o lawọn o ni i yee ṣewọde titi ti wọn fi maa ṣatunṣe to yẹ lori ọrọ yii.

Nigba ti ọkunrin naa mu lẹta jan-an-ran-jan-an-ran ti wọn kọ lori ọrọ naa le alaga apapọ lọwọ, o ni awọn mọ-ọn-mọ ṣeto iwọde naa lati ṣe kongẹ ayẹyẹ afihan ti wọn ṣe lọjọ naa ni, ki Tinubu atawọn agbaagba ẹgbẹ le mọ pe awọn ọdọ o si lẹyin wọn ninu iyansipo ẹlẹsin kan naa ti wọn ṣe ọhun.

Apa kan lẹta naa ka pe: “Loootọ ni ẹtọ lati ṣepinnu wa, ṣugbọn ko daa lati ṣe iru ipinnu bẹẹ lọna to ta ko laakaye ati ironu ọpọ ọmọ orileede yii, paapaa niru asiko ti awuyewuye wa laarin awọn ẹlẹsin Musulumi ati ti Kirisitẹni lagbegbe Ariwa orileede yii.

“Ọrọ yii kan wa, awa la si pọ ju laarin awọn to maa dibo fẹgbẹ APC, tori ẹ lo ṣe ya wa lẹnu pe iru ipinnu yii waye lai wo akoba to le ṣe fun ẹgbẹ wa lasiko ibo.

“Awa o gba, a o si fara mọ ki aarẹ ati igbakeji aarẹ jẹ ẹlẹsin kan naa. Awa ọdọ Hausa-Fulani koro oju si iyansipo Kashim Shetima gẹgẹ bii oludije pẹlu Tinubu, ẹ tete jawọ laapọn ti ko yọ, ẹ da omi ila  kana. Awọn ọmọọya wa ti wọn jẹ ẹlẹsin Kirisitẹni gbọdọ ni ẹtọ ninu iṣakoso Naijiria, ko si yẹ ka sọ ẹgbẹ APC di ẹgbẹ ti ko bikita fun imọlara awọn araalu lori ọrọ ẹsin.”

Bẹẹ ni wọn sọ.

Leave a Reply