Faith Adebọla
Yatọ si iroyin kan to n ja ranyin lori atẹ ayelujara laipẹ yii, nibi tawọn kan ti n sọ pe ẹgbẹ awọn agbaagba ilẹ Yoruba nni, Afẹnifẹre ti buwọ lu erongba Aṣiwaju Bọla Tinubu lati jade dupo aarẹ orileede yii ninu eto idibo gbogbogboo to n bọ, ẹgbẹ naa ni iroyin ọhun ki i ṣe ootọ, awọn o fọwọ si Tinubu, bẹẹ lawọn o ti i fọwọ si ẹnikẹni titi dasiko yii.
Atẹjade kan ti Alamoojuto eto ibanisọrọ fun ẹgbẹ Afẹnifẹre, Ọgbẹni Ṣọla Lawal, fi lede lorukọ ẹgbẹ naa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, sọ pe ọrọ iku ojiji to mu Ọgbẹni Yinka Odumakin to jẹ ọkan pataki oloye ẹgbẹ naa lọ lawọn ṣi n daro rẹ lọwọ, awọn o ba ẹnikẹni sọrọ to jẹ mọ a n dupo aarẹ debi tawọn aa fọwọ si ẹnikẹni.
Ṣe laipẹ yii ni ọrọ ọhun fọn sori atẹ ayelujara lẹyin abẹwo ibanikẹdun ti agba oloṣelu ẹgbẹ APC ati gomina ipinlẹ Eko nigba kan nni, Oloye Bọla Ahmed Tinubu, lọọ ṣe si Oloye Ayọ Adebanjọ fun ti ipapoda Yinka Odumakin. Wọn ni Dayọ Adeyẹye to n ṣagbatẹru eto ipolongo fun Tinubu lati dupo aarẹ sọ pe lasiko abẹwo ọhun ni Alagba Fasọranti ti kede pe ẹgbẹ Afẹnifẹre ti buwọ lu Tinubu fun ipo aarẹ ti wọn lo fẹẹ dije rẹ.
Ṣugbọn ẹgbẹ naa ni irọ ni, ko soootọ kan ninu ọrọ naa, tori niṣe lawọn so gbogbo igbokegbodo ati igbesẹ tawọn n ti la silẹ tẹlẹ rọ na, ọrọ ti iku Odumakin lo ṣi ba awọn bayii.
Yatọ siyẹn, wọn ni Alagba Reuben Fasọranti tawọn kan sọ pe oun lo fọkan Tinubu balẹ fun ti idije dupo aarẹ ọhun, ti fa ipo aṣaaju ẹgbẹ le Oloye Ayọ Adebanjọ lọwọ lati bii ọsẹ mẹta ṣaaju asiko yii, lẹyin ti wọn ti fọdun mejila tukọ akoso ẹgbẹ naa, ko le waa jẹ awọn ni wọn maa tun sọrọ lorukọ ẹgbẹ lati fọwọ si ẹnikẹni fun ipo aarẹ.
Ẹgbẹ ọhun ni iwa ailọwọ ni, iwa aibikita ni, bẹẹ lawọn o si reti iru nnkan bẹẹ pe ki Ọmọọba Dayọ Adeyẹye maa sọrọ nipa ibuwọlu ẹgbẹ Afẹnifẹre fun eto oṣelu Tinubu niru asiko yii, ti ẹgbẹ naa n sọfọ iku ojiji to mu ẹni wọn lọ.
Wọn niṣe lo yẹ ki Adeyẹye si ba awọn kẹdun lasiko yii, ko si fi ọrọ ti oṣelu ati ipolongo eyikeyii rọ na, tori ara ẹgbẹ Afẹnifẹre ṣaa loun naa nigba kan, ọrẹ lo si jẹ si oloogbe tawọn n ṣedaro ẹ yii.