Mọto ti wọn ni ki Kazeem fọ ni Festac lo n gbe sa lọ tọwọ fi ba a n’Idoroko

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

 

Bi Kazeem Ọlanrewaju tẹ ẹ n wo yii ṣe n fi mọto sare, ti mọto ọhun ko si tun ni nọmba idanimọ kankan lo fu awọn ọlọpaa lara lagbegbe Idiroko, lọjọ kẹfa, oṣu kẹrin, ọdun 2021 yii. Bi wọn ṣe da a duro to tun fere ge e si tun jẹ idi kan ti wọn fi mọ pe ọwọ rẹ ko mọ rara.

Mọto Venza ni Kazeem n wa lọjọ naa gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, ṣe sọ. Ki i ṣe pe wọn ko gba nọmba si mọto ọhun, APP 775 GB gan-an ni nọmba rẹ, Kazeem to n ṣiṣẹ abani-fọ-mọto lo yọ ọ kuro nigba to fẹẹ gbe e sa lọ.

Alaye to ṣẹ fawọn ọlọpaa to to da a duro ni pe, ibi kan ti wọn ti n fọ mọto loun ti n ṣiṣẹ ni Festac, l’Ekoo.

O ni ẹni to ni mọto yii ni koun fọ ọ ni, o si lọọ gẹrun ẹ nitosi ibẹ. Ki kọsitọma naa too pada de, Kazeem loun gbe mọto naa pẹlu ero ọkan ati lọọ ta a.

O ni ile Olominira Benin loun fẹẹ ta a si, ibẹ naa loun n gbe e lọ toun fi yọ nọmba rẹ kuro.

Ọna Idiroko to loun fẹẹ gba debẹ lo ni oun wa toun fi ko sọwọ awọn ọlọpaa.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Ajogun, ti ni ki wọn wadii ọkunrin yii wo daadaa lati mọ iru iṣẹ buruku to ti ṣe ri, bẹẹ lo ni wọn yoo taa ri ẹ sipinlẹ Eko to ti jale, nitori ibẹ naa ni wọn yoo ti gbe e lọ sile-ẹjọ.

Leave a Reply