Ọlawale Ajao, Ibadan
Nitori bi awọn alaṣẹ ileewe giga naa ṣe kọ lati maa sanwo oṣu wọn ni ibamu pẹlu ilana owo-oṣu tuntun ti ijọba gbe kalẹ, ẹgbẹ awọn agba oṣiṣẹ Poli Ibadan, iyẹn Senior Staff Association of The Polytechnic (SSANIP), bẹrẹ iyanṣẹlodi.
Lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni iyanṣẹlodi ọlọjọ mẹta ọhun bẹrẹ, yoo si wa sopin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Nigba ti wọn n kede ipinnu naa nibi ipade apapọ awọn ọmọ ẹgbẹ yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja, ẹgbẹ SSANIP sọ pe nitori bi awọn alaṣẹ ileewe naa ṣe kọ lati ṣafikun owo-oṣu awọn ni ibamu pẹlu ilana owo-oṣu tuntun tijọba apapọ gbe kalẹ lawọn ṣe fẹẹ yanṣẹ lodi.
Gbogbo ohun to jẹ ipenija fawọn agba oṣiṣẹ yii lẹnu iṣẹ, titi dori ọrọ eto ilera ni wọn sọrọ le lori nibi ipade ọhun.
Bakan naa ni wọn bu ẹnu atẹ lu bi igbimọ awọn alaṣẹ ileewe naa ṣe kọ lati tẹle gbogbo adehun to jọ wa laarin wọn pẹlu ẹgbẹ awọn agba oṣiṣẹ poli naa latọdun 2013, eyi to da lori bi awọn oṣiṣẹ naa ko ṣe ni i maa ṣiṣẹ-erin-jẹjẹ-ẹliiitri atawọn nnkan mi-in.
Alaga ẹgbẹ SSANIP ni Poli Ibadan, Ọgbẹni Akinọla Gbenga, sọ pe ikilọ lasan lawọn fi iyanṣẹlodi ọlọjọ mẹta yii ṣe, ọjọ mẹrinla pere lawọn si fun awọn alaṣẹ ileewe naa lati wa nnkan ṣe si ọrọ awọn, wọn ni bi ọjọ mẹrinla ọhun ba pe ti ko si ayipada, nnkan ti awọn yoo ba wọn fa nigba naa ko ni i ba wọn lara mu rara.