Awọn ṣọja gbe oku awọn ti wọn pa ni Lẹki pamọ ni o

Ẹgbẹ alaaanu agbaye ti wọn n pe ni Amnesty International kede fun gbogbo aye lanaa pe gẹgẹ bii iṣe awọn agbofinro to ba ṣebajẹ, niṣe ni awọn ṣọja Naijiria ti wọn yinbọn lu awọn ọdọ ni Lẹki gbe oku awọn ti wọn pa pamọ, ko ma di pe awọn eeyan yoo ri wọn, tabi pe kamẹra kan yoo ya fọto awọn okui naa. Bẹẹ o kere tan, eeyan mejila ni wọn yinbọn pa ni Lẹki yii.

Ẹgbẹ alaaanu agbaye yii ni lapapọ, awọn eeyan mẹrindinlọgọta ni won ti ba iṣelẹ SARS yii lọ, to si jẹ ni ọjọ Iṣẹgun ijẹta yii ni mejidinlogoji ku. Ajọ nla yii ni oju awọn lọrọ yii ṣe, awọn si wa ni ọpọ ibi ti orọ yii ti ṣẹlẹ lati mọ ohun to n lọ ni. Wọn ni ko si alaye kan ti ẹnikẹni le ṣe fi lodi si ohun ti awọn n sọ.

Awọnn ẹgbẹ yii ni gbogbo fidio ti awọn ri ya, ọrọ ti awọn ba awọn eeyan sọ, ati eyi to ṣoju awọn eeyan awọn funra wọn fihan pe laarin aago meje ku iṣẹju mẹẹdogun si aago mẹsan-an alẹ Ọjo Iṣẹgun, Tusidee, ogunjọ oṣu yii, awọn ṣọja ṣina ibọn fun awon afehonuhan ti wọn n beere fun iparẹ awọn ọlọpaa SARS, ati ijọba rere, wọọrọwọ, lai bẹni kan ja, tabi di ẹnikẹni lọwọ.

Wọn ni ko si ohun ti yoo dara ju ki ijọba Naijiria gbe iwadii to lagbara dide, ki wọn le fi han aye pe awọn kọ lawọn ran awọn ṣọja apaayan naa niṣẹ.

Leave a Reply