Awọn ṣọja yoo yọju si igbimọ to n gbọ ẹjọ rogbodiyan to ṣẹlẹ ni Lẹki

Aderounmu Kazeem

Loni-in Satide, ọjọ Abamẹta, yii lawọn ẹṣọ ologun ilẹ wa yoo yọju siwaju igbimọ to n gbọ ejọ nipa rogbodiyan to ṣẹlẹ lori iwọde SARS ni Lẹkki.

Saaju asiko yii ni Ọgagun Ọṣọba Ọlaniyi, ẹni ti ṣe agbẹnusọ fun ikọ ologun 81Division, l’Ekoo, ti sọ pe awọn ṣọja ko ni i yọju ayafi ti ijọba Eko, to ran awọn niṣẹ ba kọwe sawọn wi pe ki awọn lọọ yọju sigbimọ ọhun.

Ni bayii, o jọ pe awọn ṣọja ti yi ipinnu wọn pada bayii, bẹẹ ni wọn yoo sọ bọrọ ṣe jẹ niwaju igbimọ Adajọ-fẹyinti Doris Okuwobi.

ALROYE gbọ pe lara awọn eeyan to lẹnu laarin ilu lo ba ileeṣẹ oloogun sọrọ wi pe ki wọn lọọ sọ bọrọ ṣe jẹ, ki wọn le wẹra wọn mọ.

Bakan naa la gbọ pe, lara awọn nnkan to fẹẹ mu awọn ṣọja ọhun yọju laaarọ yii ni pe, ohun itiju lo maa jẹ fun ijọba Eko to gbe igbimọ ọhun silẹ, ti awọn ṣọja ba kọ lati yọju, bẹẹ ni yoo jẹ ipalara fun eto iṣelu.

Omi-in ti a tun gbọ ni pe, o ṣe pataki ki ileeṣẹ oloogun paapaa wẹ ara ẹ mọ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn lori bi wọn ṣe kọlu awọn to n ṣewọde ni too-geeti, Lẹkki, l’Ekoo.

“Latigba ti iṣẹlẹ ọhun ti waye lawọn eeyan ti n foju abuku wo ileeṣẹ ologun, o si ṣe pataki ki wọn wẹra wọn mọ lori ikọlu ọhun. Ọkan lara awọn araalu lo sọ ọ.

 

Leave a Reply