Awọn aṣọbode gba ọpọlọpọ irẹsi ati aṣọ lọwọ awọn onifayawọ l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Ọtalelẹẹẹdẹgbẹta ati mẹrin aṣọ, ọpọ irẹsi ilẹ okeere, bata ati baagi, lawọn aṣọbode ilẹ wa, ẹka ti Eko, ri gba pada lọwọ awọn onifayawọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii. Wọn lowo awọn ẹru naa to miliọnu lọna ọgọrun-un mẹsan-an naira.

Olori ikọ ileeṣẹ aṣọbode ti wọn pe ni Strike Force Unit, DC Ahmadu Bello Shaibu, lo ṣafihan awọn ẹru ọhun nile ikẹru-si awọn aṣọbode, l’Apapa.

Ninu ọrọ to sọ nibi afihan ọhun, Shaibu ni ẹgbẹfa (1, 200) baagi irẹsi, ẹgbẹrun lọna ọgbọn (30,000) baagi, ẹgbẹta le diẹ bata atawọn nnkan ẹṣọ mi-in lawọn onifayawọ naa ko wọlu, wọn waa purọ fawọn agbofinro pe ẹrọ iranṣọ atawọn irinṣẹ kan lawọn n ko kiri.

Gẹgẹ bi Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa ṣe sọ, wọn ni Shaibu sọ pe pupọ awọn ẹru ọhun nijọba ti fofin de, o loun fura pe boya asiko ọdun ta a wa yii lo mu kawọn afurasi ọdaran onifayawọ naa lọwọ ninu iwa to le sọ orileede yii di aakitan nla tawọn orileede yooku yoo maa ko aloku atawọn ọja ti o bofinmu, wọ.

Ọga aṣọbode naa ni awọn ẹru ti wọn gba yii maa di tijọba kẹyin ni, tori awọn maa wọ awọn afurasi naa atawọn to ran wọn niṣẹ lọ si kọọtu, awọn si maa ni kile-ẹjọ paṣẹ gbigbẹsẹ le awọn ẹru ọhun.

Ni bayii, o ni iwadii ti bẹrẹ lati mọ awọn olokoowo to ran awọn to kẹru ofin ọhun niṣẹ.

Leave a Reply