Awọn aṣofin pariwo, wọn ni were n pọ si i l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Pẹlu bawọn were atawọn alairilegbe ṣe gba igboro Abẹokuta kan nipinlẹ Ogun, ti wọn si n fojoojumọ pọ si i, ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ naa ti ke si awọn tọrọ kan nijọba pe ki wọn wa nnkan ṣe si i.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lawọn aṣofin gbe ọrọ awọn were naa yẹwo nileegbimọ to wa l’Oke -Mosan, l’Abẹokuta.

Olori wọn, Ọnarebu Ọlakunle Oluọmọ, sọ pe iṣẹ wa fun ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn obìnrin nipinlẹ Ogun,  pẹlu awọn ẹka bii tiẹ lati ṣe lori apọju were tawọn tori ẹ pepade yii.

O lo jẹ oun ti ko ṣee dagunla si bo ṣe jẹ pe èèyàn ko le rin jinna ko too kan alarun ọpọlọ kaakiri ilu Abẹokuta.

Oluọmọ rọ Kọmiṣanna fọrọ awọn obinrin, Abilekọ Funmi Ẹfuwapẹ, pe ko pe awọn ẹka ti ọrọ yii kan, ki wọn jọ tete bẹrẹ eto lori bi wọn yoo ṣe ko awọn were atawọn to sọ titi dile naa kuro nigboro Abẹ́òkúta

Bakan naa ni wọn sọrọ lori ipo idọti ti odo ẹran Kara wa, iyẹn loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan. Awọn aṣofin bii Dare Kadiri (Igbakeji abẹnugan) Atinukẹ Bello(Akojaanu), Ganiyu Oyedeji ati bẹẹ lọ, ṣalaye pe ipo to le ko ba ilera eeyan ni ọja ti wọn ti n pa ẹran maaluu yii wa, bẹẹ, ibẹ lọpọ eeyan ti n ra ẹran ti wọn n jẹ.

 

 

Wọn rọ awọn ẹka imọtoto lati mojuto Kara, fun ilera to peye awọn eeyan kaakiri.

Leave a Reply