Awọn aṣofin Ondo ba mọlẹbi awọn to ku sinu ijamba ọkọ l’Akungba Akoko kẹdun

Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ

Ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo ti ranṣẹ ibanikẹdun si mọlẹbi gbogbo awọn to ku sinu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ niluu Akungba Akoko loṣu to kọja.

Awọn aṣofin ọhun to n jokoo fun igba akọkọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lati igba ti wọn ti pari idibo gomina to waye lọjọ kẹwaa, oṣu to kọja, fi aidunnu wọn lori iwakuwa ọkọ awọn awakọ ajagbe ni Akoko, eyi to n ṣokunfa ọpọ ijamba ọkọ to n fẹmi awọn eeyan ṣofo lagbegbe ọhun.

Aṣofin to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Guusu Iwọ-Oorun Akoko, Ọnarebu Fẹlẹmugudu Bankọle, ninu aba to fi siwaju ile ni asiko ti to fun ile-igbimọ ọhun lati gbe igbesẹ ti yoo fopin siru iṣẹlẹ bẹẹ lọjọ iwaju.

Ọnarebu ọhun ni Gomina Rotimi Akeredolu gbọdọ ko gbogbo ọja ti wọn n na lawọn oju ọna marosẹ kuro ni kiakia lọ sibomi-in, nitori aabo ẹmi awọn to n taja.

O tun rọ ijọba ipinlẹ Ondo lati ṣatunṣe gbogbo ọna to wọ ilu Akungba Akoko, ki iṣẹlẹ ijamba ọkọ to n waye lagbegbe naa le dinku jọjọ.

Abẹnugan ile, Ọnarebu Bamidele Ọlẹyẹlogun, ni oun naa fara mọ gbogbo abajade ijokoo ọjọ naa.

O ni ile-igbimọ naa ko ni i pẹ gbe igbimọ kan kalẹ ti yoo siṣẹ lori atunṣe awọn ọna Akoko ati ibi to yẹ ki wọn ko awọn ọja to wa loju ọna marosẹ lọ.

 

Leave a Reply