Awọn afẹmiṣofo dena de Buhari ni Katsina, wọn ṣe ẹṣọ alaabo meji leṣe

Faith Adebọla

Wahala awọn agbebọn afẹmiṣofo ati eto aabo to dẹnu kọlẹ lorileede wa tun gba ọna mi-in yọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ karun-un, oṣu Keje yii, nigba tawọn apaayan naa lọọ dena de ọkọ akọwọọrin ileeṣẹ Aarẹ Buhari, wọn ṣina ibọn bo bolẹ, wọn si ṣe eeyan meji leṣe ninu awọn ẹṣọ alaabo to n ṣiṣẹ pẹlu aarẹ.

Oluranlọwọ pataki si aarẹ lori eto iroyin, Mallam Garba Shehu, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi lede lalẹ Ọjọbọ, Tusidee, ọhun.

O ni ileeṣẹ Aarẹ ti ṣapejuwe iṣẹlẹ ọhun bii eyi to ba ni lọkan jẹ, awọn o si reti iru nnkan bẹẹ, bi awọn agbebọn kan ṣe bẹrẹ si i rọjo ọta ibọn lu ikọ akọwọọrin awọn ẹṣọ alaabo to n ṣọ aarẹ, awọn oniroyin, ati awọn oṣiṣẹ akanṣe, lasiko ti ikọ naa n lọ siluu Daura, nipinlẹ Katsina, lati lọọ ṣeto to yẹ lati gbalejo Aarẹ Muhammadu Buhari fun ti ayẹyẹ ọdun Ileya to maa waye lopin ọsẹ. Agbegbe Dutsinma, nipinlẹ Katsina, lawọn agbebọn naa ti kọ lu wọn.

“Awọn agbebọn naa ṣina ibọn bolẹ lati ibuba wọn, ṣugbọn awọn jagunjagun, awọn ọlọpaa ati ẹṣọ ọtẹlẹmuyẹ DSS, to wa ninu ikọ naa fibọn fesi pada, wọn si le awọn eeyankeeyan naa sa.

“Meji ninu awọn to wa ninu ikọ akọwọọrin naa fara gbọgbẹ lasiko iṣẹlẹ ọhun, ṣugbọn ko pọ, wọn si ti n gba itọju lọwọ, awọn yooku ati ikọ naa ti gunlẹ si ilu Daura.”

Gẹgẹ bi ileeṣẹ aarẹ ṣe sọ.

Leave a Reply