Awọn afọbajẹ Ibadan fọwọ si Ọlakulẹhin gẹgẹ bii Olubadan tuntun

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni gbogbo awuyewuye to ti n waye lori ẹni to yẹ ko jẹ Olubadan ilẹ Ibadan, dopin pẹlu bi awọn afọbajẹ ṣe fọwọ si Owolabi Ọlakulẹhin gẹgẹ bii Olubadan tuntun.

Laaarọ ọjọ Ẹti yii nigbimọ Olubadan, ti wọn tun jẹ afọbajẹ ilu naa, fọwọ si iyansipo Ọba Owolabi Ọlakulẹyin, nibi ipade to waye laafin Olubadan, l’Ọja’ba. Ninu gbogbo awọn afọbajẹ naa, Ọtun Balogun ilẹ Ibadan, Ọba Tajudeen Ajibọla, to jẹ igbakeji ẹni ti ipo Olubadan kan bayii nikan ni ko yọju sibi ipade pataki ọhun.

Bo tilẹ jẹ pe o han gbangba pe agba ti de si Ọba tuntun naa, nitori niṣe ni baba naa rọra n tẹ kẹjẹ kẹjẹ nigba to jade ninu jiipu alawọ dudu kan ti wọn fi gbe e wa sibi ipade ọhun. Niṣe ni awọn eeyan si n ki i ni mẹsan-an mẹwaa, ti wọn n ṣadura fun un pe yoo lo ipo naa pẹ.

Ni bayii ti Ọba Ọlakulẹhin ti yọju si awọn igbimọ afọbajẹ Olubadan, ti wọn si ti fẹnu ko pe oun ni awọn mu gẹgẹ bii Olubadan ilẹ Ibadan tuntun, igbesẹ to ku bayii ni ki wọn kọ lẹta si Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, lati fi to o leti, ko si fọwọ si orukọ naa, ki baba yii si gori oye gẹgẹ bii Olubadan tuntun.

Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan, Agba-Oye Rashidi Ladọja, to ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Ọyọ, ẹni to pe ipade ọhun gẹgẹ bii ẹni ti ipo rẹ ga ju lọ laarin awọn agba ijoye Ibadan, fidi ẹ mulẹ fawọn oniroyin nile ẹ, l’Ọjọruu, Wẹsidee, pe Ọjọbọ, Tọsidee, lawọn kọkọ fi eto ọhun si, ṣugbọn nitori bi ijoba apapọ ilẹ yii ṣe pada fi Tọsidee kun ọjọ isinmi ọdun Itunnu Aawẹ lo jẹ

kawọn sun un si ọjọ Jimọ.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹrin, ọdun yii, l’Ọtun Balogun sọ pe ọga oun ko si nipo ẹni to le jọba, nitori ko gbadun, ara ẹ ko tiẹ ya rara, ati rara ni.

O ni, “Temi ni pe ka ni suuru ki ara baba yii fi ya na, nitori baba yii ko gbadun, ara wọn ko le rara. Ẹnikẹni ko ti i foju kan baba lati ọjọ Furaidee? Awọn to lọ sile wọn paapaa ko ri wọn, wọn kan n fi tulaasi mu wọn lati ṣe gbogbo ohun ti wọn n ṣe ni. Ẹ jẹ ka ni suuru fun wọn ki wọn tiẹ gbadun na”.

Nigba to n fesi si ọrọ yii, Sẹnetọ Ladọja sọ pe ọrọ ko ri bi Ọba Ajibọla ṣe sọ ọ yẹn. O ni ko si idi ti wọn ṣe gbọdọ fi ohunkohun falẹ lati fi Ọlakulẹhi jẹ Olubadan, nitori ki i ṣe pe aisan n ṣe baba naa, agba to ti de si i lo fa a ti ara rẹ ko ṣe le maa ta kebe kebe bii tọmọ ogun (20) ọdun.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ‘’Gbogbo wa la fẹran alaafia. Ibi ti Ibadan daa si niyẹn. Awa Ibadan mọ baa ṣe maa n sọ nnkan to gbona janjan di tutu. O da bii igba ti omi ba gbona, to n ho gudugudu, ti gbogbo aye yoo ti maa wo o pe eleyii yoo ṣe eeyan leṣe, ti ẹnikan waa gbe omi naa mu pẹlu gbogbo hiho to n ho yẹn, ti gbogbo ẹ waa poora mọ ọn ninu. Nigba naa ni yoo too waa han si gbogbo aye pe ọrọ naa ko le to oju ti awọn fi n wo o tẹlẹ.

“Tẹgbọn-taburo ni gbogbo wa, koda, titi dori Tajudeen to sọrọ yẹn. Boya ohun ti ko ye Taju niyẹn. Nigba ta a ba pade lọjọ Jimọ, boya o maa tubọ ye e.

Ṣugbọn ni bayii ti baba naa ti yọju, ti awọn igbimọ Olubadan (yato si Ọtun Balogun) ti fẹnu ko pe Ọlakulẹhin ni awọn mu bii Olubadan tuntun, gbogbo awuyewuye to ti n waye lori oye Olubadan ti rodo lọọ mumi bayii.

Leave a Reply