O tan! Adajọ ju Bobrisky sẹwọn oṣu mẹfa

Ẹwọn oṣu mẹfa lai si anfaani fun owo itanran ni Onidaajọ Abimbọla Awogbọrọ ti ile-ẹjọ giga to wa ni Ikoyi, niluu Eko, ju Idris Okunlẹyẹ, ti gbogbo eeyan mọ si Bobrisky si, nigba ti idajọ waye lori ẹsun ṣiṣẹ owo ilẹ wa baṣubaṣu ti wọn fi kan an waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

Lasiko ti igbẹjọ naa n lọ lọwọ ni Adajọ Awogbọrọ beere lọwọ Idris, ti gbogbo eeyan mọ si Bobrisky, to maa n mura bii obinrin, to si ti fẹrẹ paarọ gbogbo ẹya ara rẹ si ti obinrin tan, sọ pe ọkunrin ni oun, oun ki i ṣe obinrin.

Ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ti wọn mu-un gan-an ni adajọ ni ki ẹwọn oṣu mẹfa naa bẹrẹ.

Ọsan Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, lawọn ẹṣọ ajọ to n gbogun ti iwa jibiti lilu, ṣiṣẹ owo ilu mọkumọku ati awọn iwa ibajẹ to jẹ mọ ti owo ilẹ wa, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ẹka ti ipinlẹ Eko, lọọ fọwọ ofin mu Bobrisky, wọn lo n na owo Naira bii ẹlẹda, o fabuku kan owo beba ilẹ wa, pẹlu bo ṣe n nawo yẹlẹyẹlẹ loju agbo, to n tẹ owo naa mọlẹ lọ mọlẹ bọ, to si n ṣe owo naa bii beba lasan.

Amọ lọjọ keji ti wọn mu un, iyẹn Tọsidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹta, wọn fun Bobrisky ni beeli, bo tilẹ jẹ pe iwadii lori ẹsun ti wọn fi kan an ṣi n tẹsiwaju, amọ titi tilẹ ọjọ naa fi ṣu, ko ṣee ṣe lati san beeli rẹ, wọn ni ko kunju oṣuwọn ohun ti wọn n beere fun.

Alukoro EFCC l’Ekoo, Ọgbẹni Dele Oyewale, to sọrọ lori iṣẹlẹ yii lọjọ Tọsidee, ni loootọ ni Bobrisky ṣi wa lakata awọn, ati pe ko ṣee ṣe fun un lati kaju beeli tawọn fun un.

Oyewale ni: “Aṣa palapala to lodi sofin ti Bobrisky hu nibi ayẹyẹ ikojade fiimu tuntun ti wọn pe akọle rẹ ni ‘Ajakaju’, eyi ti Ẹniọla Ajao ṣẹṣẹ ṣe, ti afihan akọkọ rẹ waye ni gbọngan iworan Film One Circle Mall, lagbegbe Lẹkki, nipinlẹ Eko, lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, lo mu ki EFCC ke si Bobrisky lati foju kan wa, ta a si fi pampẹ ọba gbe e.

“Iwadii wa fidi rẹ mulẹ pe eyi ko ni igba akọkọ ti afurasi naa yoo maa huwa abuku si owo Naira, eyi to lodi sofin banki apapọn ilẹ wa’’.

Tẹ o ba gbagbe, ibi afihan fiimu kan ti Ẹniọla Ajao ṣe ti wọn pe ni ‘Ajakaju’ ni ọmọkunrin to maa n pe ara rẹ ni Mummy of Lagos yii lọ lo ti n fọn owo bii ẹlẹda. Eyi ni ajọ to n ri si iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku (EFCC), tori ẹ mu un, pẹlu awọn ibi apejẹ mi-in to ti lọ to ti n fọn owo, ti wọn si ni o tun n tẹ owo ọhun mọlẹ, lọjọ kẹta, oṣu yii, ti wọn si foju rẹ ba ile-ẹjọ lọsẹ to kọja.

Bobrisky ko fakoko kootu ṣofo to fi ni oun jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan oun yii, to si ni ki ile-ẹjọ ṣiju aanu wo oun pẹlu ileri pe oun ko ni i ṣe bẹẹ mọ, ati pe oun yoo lo anfaani pe oun jẹ ilu-mọ-ọn-ka lati fi polongo fun awọn eeyan pe ki wọn yee ṣe owo ilẹ wa baṣubaṣu.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu yii, lo yẹ ki idajọ naa waye, ṣugbọn nitori isinmi Ramadan ti ijọba apapọ kede lo fa a ti wọn ko fi dajọ naa, ko too di pe idajọ naa waye lọjọ kejila, oṣu yii.

 

 

Leave a Reply