Ọgbọn miliọnu Naira lawọn agbebọn to ji akọroyin Channels gbe n beere fun

Monisọla Saka

Awọn agbebọn ti ji Ọgbẹni Joshua Rogers, ti i ṣe oniroyin nileeṣẹ tẹlifiṣan Channels, ẹka ti ipinlẹ Rivers gbe nile ẹ to wa ni Rumuosi, ijọba ibilẹ Obio/Akpor, nipinlẹ Rivers, lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

Nile ijọba ipinlẹ Rivers, ni Rogers ti n ṣiṣẹ fun ileeṣẹ tẹlifiṣan to gba a siṣẹ, amọ tawọn ọdaju ẹda yii da a lọna lasiko to n dari lọ sile lati ibi iṣẹ.

Ko too di pe yoo sọkalẹ ninu ọkọ rẹ lawọn atilaawi ti na ibọn si i. Ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ti wọn dena de e yii ni wọn gbe e pẹlu mọto rẹ lọ sibi tẹnikan ko mọ.

Ọkunrin kan to ba akọroyin Punch sọrọ, amọ to ni ki wọn forukọ bo oun laṣiiri fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni wọn ji ọkunrin naa gbe lọ, o ni, “Bẹẹ ni, lalẹ ana ni wọn fi mọto rẹ ji i gbe lọ lati ile rẹ to wa ni Rumuosi. A n rawọ ẹbẹ sawọn ajinigbe yii lati tu u silẹ ni kiakia ati lalaafia. Akọroyin lasan lọkunrin yii, ki i ṣe baba olowo, nitori bẹẹ ni mi o ṣe mọdi ti wọn fi ji i gbe.

Koda gan-an, l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, kan naa ni ọkunrin yii lọọ ṣoju ileeṣẹ wọn nibi ayẹyẹ kan ti wọn ṣe ni Ndoni, nijọba ibilẹ Ogba-Egbema-Ndoni, nibi ti Gomina Siminalayi Fubara, ti ipinlẹ naa ti lọ ṣi ile iwosan alabọọde kan ti PAMO Educational Foundation, ti i ṣe ti gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ, Dokita Peter Odili, ṣẹṣẹ kọ fun wọn”.

Wọn ni awọn agbebọn ti wọn ji ọkunrin yii gbe ti pe iyawo ọkunrin naa, ọgbọn miliọnu Naira (30M) ni wọn si lawọn yoo gba ko too le gba itusilẹ.

 

Leave a Reply