Awọn agba Musulumi ni ki imaamu agba fipo silẹ ni mọṣalasi Ikarẹ-Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Lati bii ọjọ diẹ sẹyin ni ara ko ti rọ okun ti ko si tun rọ adiẹ ninu mọṣalasi gbogbogboo to wa niluu Ikarẹ Akoko, nipinlẹ Ondo, pẹlu bi awọn agba Musulumi ṣe ko ara wọn jọ, ti wọn si ni awọn ti jawee gbele-ẹ fun ẹni Imaamu agba ile-ijọsin ọhun, Alaaji Abubakri Abass Muhammed, latari awọn ẹsun iwa afojudi, aini afojusun ati kikuna lati gbe igbesẹ lori bi a awọn Musulumi agbegbe Ikarẹ yoo ṣe wa ni irẹpọ ti wọn fi kan an.

ALAROYE gbọ pe Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni igbimọ to ga ju lọ ninu ẹsin Musulumi, ẹka tilu Ikarẹ fun imaamu agba ọhun ni lẹta, ‘a yọ ọ kuro nipo, ti wọn si paṣẹ fun un lati jọwọ gbogbo ẹru ijọ to wa ni ikawọ rẹ fun ẹni to jẹ akọwe igbimọ naa lẹyẹ-o-ṣọka nitori pe awọn ko ni i gba a laaye ko waa ṣaaju irun Jimọ ti yoo waye ninu mọsalasi ọhun lọjọ keji ti i ṣe ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa, yii.

Ọrọ iyọninipo yii ti fẹẹ maa mu rogbodiyan lọwọ ki igbimọ to n bojuto ẹgbẹ awọn Imaamu ati Afaa nipinlẹ Ondo, eyi ti Alaaji Ahmed Aladesawe, jẹ adari rẹ too sare fi atẹjade sita pe awọn ti wọgi le lẹta iyọninipo naa.

Ninu iwe ti akọwe wọn, Alaaji Rasheed Akerele (Imaamu Supare Akoko), kọ lo ti ni awọn gbe igbesẹ naa ni ibamu pẹlu ibi ti ijọba ipinlẹ Ondo yanju ọrọ ọhun si tẹlẹ lasiko ti iru iṣẹlẹ bẹẹ kọkọ jẹ yọ lọdun to kọja.

Awọn eeyan ti kọkọ ro pe o ṣee ṣe ki irun Jimọ ọsẹ yii ma ṣee ki ninu mọṣalasi ọhun latari ede aiyede naa, ọpọ olujọsin ni wọn si ti gba kamu pe ṣe nijọba yoo tun ti ilẹkun ibẹ pa gẹgẹ bi wọn ti ṣe lọdun to kọja nigba ti rogbodiyan ọhun ṣẹṣẹ bẹrẹ.

Iyalẹnu lo jẹ fawọn eeyan nigba ti wọn ri awọn agbofinro atawọn ẹṣọ alaabo mi-in ti wọn duro wamuwamu yi agbegbe Ọja Ọba, nibi ti mọṣalasi nla ọhun wa ka, ki aago mejila ọsan ọjọ Jimọ too lu.

 

Koda, imaamu ti wọn lawọn rọ loye gan-an lo tun ṣaaju irun laarin asiko ti irun Jimọ kiki fi waye, ti ko si si ẹnikan to le fa wahala titi ti wọn fi pari.

Leave a Reply