Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii ni ẹgbẹ oṣiṣẹ ti ijọba ipinlẹ Ekiti gba siṣẹ, ti wọn n gba ilẹ niluu Ado-Ekiti, ṣe iwọde ta ko bi ijọba ipinlẹ naa ṣe n fi iya owo oṣu jẹ wọn.
Awọn ẹgbe oṣiṣẹ naa ti gbogbo wọn jẹ obinrin, ti wọn ko si din ni ọgọrun wọn sọ pe awọn ṣe iwọde naa lati ke pe ijọba ki wọn fi kun owo oṣu awọn to jẹ ẹgbẹrun marun-un naira.
Wọn ni o ti to ki ijọba fi kun owo-oṣu awọn lati ẹgbẹrun marun-un naira si ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira, ko le ba ti awọn oṣiṣẹ to ku labẹ ijọba ipinlẹ naa mu.
Iwọde naa ni wọn bẹrẹ ni deede aago meje aarọ, lati gbangan Fajuyi to wa niluu Ado-Ekiti, ti wọn si gbe patako oriṣiiriṣii dani.
Lara awọn akọle to wa lara patako ọhun ni “Ẹ dawọ sisan owo oṣu kekere fun awa agbalẹ” “Ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira ni owo oṣu to kere ju ju lọ fawọn oṣiṣẹ.” ” Gomina Kayọde, jowọ, ma fi wa silẹ.” “Iya n jẹ wa.” “Owo oṣu wa ti kere ju, ẹgbẹrun marun-un naira ko tẹ wa lọrun.” ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Olori awọn oṣiṣẹ agbalẹ, Titilayo Faweya, ṣalaye pe awon ṣe iwọde naa lati ta ko ipinnu ijọba ati bi iya ṣe n jẹ awọn ọmọ ẹgbẹ awọn.
O ni awọn ọmọ ẹgbẹ oun ti ni suuru latigba ti Gomina Kayọde Fayẹmi ti ṣe ileri fun awọn ni ọdun mẹta sẹyin pe oun yoo fi kun owo oṣu awọn ni kete toun ba ti gun ori aleefa.
“Idi pataki ti a fi ṣe iwọde yii, ni pe ijọba ipinlẹ Ekiti n fiya jẹ wa pupọ, ki i ṣe pe awọn ọmọ ẹgbẹ wa n ba ijọba ja, tabi boya a ko fi ọkan ijọba balẹ, ṣugbọn awọn ẹgbẹ wa ti ni suuru to.”
“Ẹgbẹrun marun-un naira pere ni owo oṣu wa, ti ẹ ba gbọ iye ti wọn n ta gaari lọja bayii, bawo ni a ṣe fẹẹ fi owo kekere tijọba yii n san fun wa bọ awọn ọmọ wa, awọn to pọ ju lara wa jẹ opo ti ko ni ọkọ sile.”
Nigba to n ba awọn agbalẹ naa sọrọ, Kọmiṣanna fun eto ayika nipinlẹ Ekiti, Arabinrin Iyabọ Fakunle, sọ pe gbogbo nnkan ti awọn oṣiṣẹ naa sọ ni oun yoo fi to Gomina Kayọde Fayẹmi leti.