Awọn agbebọ ya wọ ile Ọjọgbọn Banji Akintoye l’Akurẹ

Jọkẹ Amọri

Ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ to kọja yii ni awọn agbebọn kan ya bo ile Olori ẹgbẹ to n ja fun ominira Yoruba, Ilana Oodua, Ọjọgbọn Bamiji Akintoye, niluu Akurẹ, nipinlẹ Ondo.

Gẹgẹ bi atẹjade ti agbẹnusọ baba naa, Ọgbẹni Maxwell Adelẹyẹ, fi sita lo ti sọ pe o jẹ ẹdun ọkan fawọn lati kede pe awọn kan lọ sile olori ẹgbẹ to n ja fun ominira Yoruba, Ọjọgbọn Bamiji Akintoye, ni ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ to kọja, ti wọn si yinbọn si ita ati gbogbo inu ile naa.

Ibọn AK47 lo ni awọn ri ọta rẹ lẹyin ti wọn ja bọ nibi ori aja ti awọn eeyan naa yinbọ si.

Adelẹyẹ ni awọn ti fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, ṣugbọn wọn ko ti i mu ẹnikẹni lori ọrọ naa. Ọjọgbọn Akintoye ko si ninu ile naa lasiko ti iṣẹlẹ aburu yii ṣẹlẹ.

Leave a Reply