Awọn agbebọn ji aburo ọba alaye gbe ni Kwara, igba miliọnu ni wọn n beere

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Abamẹta Satide, opin ọsẹ to kọja yii, ni awọn awọn agbebọn ya wọ agbegbe kan niluu Ọlla, nijọba ibilẹ Isin, nipinlẹ Kwara, ti wọn si ji aburo ọba alaye ilu naa Oni-jay, gbe lọ. Ni bayii, wọn ti n beere fun igba miliọnu naira owo itusilẹ lọwọ awọn mọlẹbi.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago meje alẹ ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ, ni awọn agbebọn naa da Oni-Jay lọna pẹlu mọto Hillux funfun rẹ lasiko to n bọ lati inu iko kan to n da ni agbegbe naa. Awọn tọrọ naa ṣoju wọn sọ pe bi wọn ṣe da ọkunrin naa duro ni wọn bẹrẹ si i yinbọn soke lati fi dẹruba awọn olugbe agbegbe naa, ati pe ọmọkunrin naa ba wọn lo agidi, eyi lo mu ki wọn ṣe e leṣe, ti ẹjẹ si kun gbogbo ara mọto rẹ, eyi to fi han pe wọn ti ṣe e basubasu.

Ko pẹ ti wọn gbe e denu igbo, ni wọn pe mọlẹbi, ti wọn si n beere fun igba miliọnu naira owo itusilẹ ṣugbọn awọn mọlẹbi dunaadura pẹlu wọn, ti wọn si sọ pe miliọnu mẹwaa lawọn le ri tu jọ. Ibẹru-bojo ti waa gbilẹ niluu Ọlla bayii, tawọn ẹṣọ alaabo si ti kan lu igbo lati doola ẹmi aburo Kabiyesi, Onijala tilu Ọlla, ti wọn jigbe ọhun.

Iroyin to tun fara pẹ ẹ ni alẹ ọjọ Abamẹta yii kan naa ni awọn agbebọn ti wọn tun ji gbajumọ oniṣowo kan Alaaji Fatima, to ni ileeṣẹ ti wọn ti n pọnmi ta niluu Sosoki, nijọba ibilẹ Asa, nipinlẹ Kwara, gbe lọ pẹlu awọn oṣiṣẹ rẹ mẹjọ miiran. Titi di akoko ta a n ko iroyin yii jọ, awọn mọlẹbi ko ti i gbọ nnkan kan nipa wọn.

 

Leave a Reply