Awọn agbebọn ji gbajumọ oniṣowo kan gbe ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, oṣẹ yii, ni awọn ajinigbe ji gbajumọ oniṣowo kan, Alaaji Jamiu Olawale, gbe lọ ni agbegbe Igbo Aran, Aboto Ọja, nijọba ibilẹ Asa, nipinlẹ Kwara, awọn ọlọpaa ati fijilante ni awọn ti n dọdẹ awọn ajinigbe ọhun lati doola ẹmi Ọlawale.

ALAROYE gbọ pe Ọlawale lọ sinu oko rẹ pẹlu ọmọ rẹ ẹni ọdun mẹjọ, ṣugbọn nigba ti wọn n dari bọ ni awọn ajinigbe da wọn lọna, ti wọn si ji oniṣowo naa lọ. Gbajumọ oniṣowo epo rọbi ni wọn pe arakunrin ọhun, to si ni ileepo meji, ọkan wa ni Amọyọ, ti ikeji si wa ni Olulade, niluu Ilọrin. Ni kete ti wọn ji ọkunrin naa gbe tan ni wọn gbe e sinu ọkọ wọn, ti wọn si wa a lọ si opopona Ira-Ọffa, nipinlẹ Kwara.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun akọroyin wa, o ni ileeṣẹ ọlọpaa ati ẹsọ alaabo fijilante ti ya bo inu igbo lati doola ẹmi gbajumọ oniṣowo ọhun.

Leave a Reply