Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, ni awọn agbebọn ya bo agbegbe ikorita Oko, niluu Omu-Aran, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, nipinlẹ Kwara, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn leralera, ki wọn too ji iya ati ọmọ ẹ meji gbe lọ.
ALAROYE gbọ pe iya ati awọn ọmọ meji ti wọn jigbe ọhun jẹ iyawo atawọn ọmọ gbajumọ elepo rọbi kan niluu Omu-Aran.
Ni nnkan bii aago meje alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ni wọn ni iṣẹlẹ naa waye, ṣọọbu ni awọn mẹtẹẹta ti wọn ji gbe naa wa ki wọn too ji wọn gbe.
Lakooko tawọn ajinigbe naa n rọjo ibọn, ọlọkada kan fara gbọta, wọn si sare gbe e lọ sileewosan kan ti wọn ko darukọ niluu naa.
Titi di akoko ta a n ko iroyin yii jọ, awọn agbebọn ọhun ko ti pe mọlẹbi lati beere fun owo itusilẹ.