Titi di ba a ṣe n sọ yii ni wọn ṣi n wa awọn oṣiṣẹ aarẹ tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, tawọn agbebọn ji gbe lasiko ti wọn n lọ sibi iṣẹ wọn ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Gẹgẹ bi iweeroyin Punch ṣe sọ, Ọbasanjọ Holdings, to wa loju ọna Kọbapẹ, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode ni wọn ti dena de awọn eeyan naa.
Abule kan ti wọn n pe ni Seseri, ni wọn ti pada mu wọn lẹyin ti wọn dana ibọn bo ọkọ Hilux ti wọn wa ninu rẹ, ti wọn si ko wọn lọ ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
A gbọ pe alamojuto ọrọ owo, ayewe-owo-wo agba ati manija kan ni awọn agbebọn naa ji lọ, ti wọn ko si ti i mọ ibi ti wọn wa di ba a ṣe n sọ yii
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ. O ni ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ni wọn ko awọn eeyan naa lọ.