Awọn agbebọn ji wolii Ṣẹlẹ meji lọ lasiko ti wọn n ṣe iṣọ oru lọwọ ni Wasinmi

Ọrẹoluwa Adedeji

Titi di ba a ṣe n sọ yii ni wọn ṣi n wa awọn ọmọ ijọ Sẹlẹ meji kan tawọn agbebọn lọọ ji gbe ninu ṣọọṣi lasiko ti wọn n ṣe iṣọ oru lọwọ ni Wasinmi, nijọba ibilẹ Ewekoro, nipinlẹ Ogun, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
ALAROYE gbọ latẹnu olori ijọ naa, Oluwatomisin Ehuwaojomọ, pe Igbakeji oluṣọagutan ijọ naa, Oluwaṣeun Ajọṣẹ ati olukọ ile-ẹkọ ọjọ isinmi, Dagunro Ayọbami, lawọn ajinigbe naa wọ lọ sinu igbo ni nnkan bii aago mejila oru ọjọ yii, ti ko si ti i sẹni to mọ ibi ti wọn wa di ba a ṣe n sọ yii.
A gbọ pe nitori pe ijọ naa wa ninu igbo to da paroparo lo jẹ ki wọn raaye ṣiṣẹ buruku naa.
Ehuwaojomọ ni lẹyin bii wakati meji ti wọn ti ko awọn eeyan naa lọ ni Ajọsẹ pe oun, ṣugbọn awọn agbebọn naa ko ba oun sọrọ, nigba to to bii igba meji ti oun ti pe wọn ni wọn ṣẹṣẹ waa ba oun sọrọ pe ki awọn san miliọnu lọna aadọta Naira bi awọn ba fẹẹ ri awọn eeyan naa pada laaye.
‘‘Mo ṣalaye fun wọn pe ko si ibi ti mo ti fẹẹ ri iru owo bẹẹ, nitori oluṣọagutan ni mi, ko si ẹni to n san owo-oṣu fun mi.’’
Ọkunrin naa ni oun ko si ninu ṣọọṣi nigba ti iṣẹlẹ yii waye, o ni inu yara loun wa ti oun n sun. O ni iṣẹlẹ ọhun ba oun lojiji gan-an ni, o waa rawọ ẹbẹ si awọn agbofinro pe ki wọn jọwọ, ba awọn wa awọn eeyan naa lawaari.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ. O ni, ‘‘Loootọ ni iṣẹlẹ ijinigbe waye lasiko ti awọn eeyan naa n ṣe iṣọ oru ni awọn ajinigbe ya wọ ṣọọṣi naa, ti wọn si ji awọn meji gbe lọ. Ṣugbọn awa naa naa ti n wa wọn kiri bayii.’’
A gbọ pe awọn ẹṣọ alaabo bii fijilante, ọdẹ atawọn mi-in ti n tu awọn inu igbo to wa lagbegbe naa lati ṣawaari awọn ti wọn ji gbe yii, ki wọn si tu wọn silẹ.

Leave a Reply