Awọn agbebọn kọ lu teṣan ọlọpaa ni Benue, wọn ba pa mẹrinla ninu wọn

Faith Adebọla

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Benue ti fidi ẹ mulẹ pe ohun ti awọn agbebọn kan ti wọn ṣakọlu si tẹṣan ọlọpaa Katsina-Ala ro kọ ni wọn ba, pẹlu bi mẹrinla lara wọn ṣe doloogbe, ti ọpọ si fara gbọta, wọn si mu awọn kan.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Benue, DSP Kate Anene sọrọ yii fawọn oniroyin lowurọ ọjọ Aiku, Sannde yii, o ni nnkan bii aago mejila oru ọjọ Satide, Abamẹta, lawọn agbebọn naa de.

Anene ni awọn afẹmiṣofo naa to aadọta, ọkada ni wọn gun wa, wọn lawọn fẹẹ waa tu awọn ẹlẹgbẹ wọn to ti wa lahaamọ awọn ọlọpaa ni teṣan naa tẹlẹ silẹ ni.

O lawọn ọlọpaa ni wọn fi pampẹ ofin mu awọn afurasi ọdaran naa lọjọ diẹ sẹyin, ti wọn fi wọn pamọ sahaamọ teṣan ọhun, tori iwadii ṣi n lọ lori wọn.

Bawọn eeṣin-o-kọku ẹda yii ṣe de ni wọn bẹrẹ si i yinbọn lati le awọn agbofinro sa tabi ki wọn pa wọn, ṣugbọn wọn lawọn ọlọpaa naa ko tura silẹ rara, faya-fọ-faya ni wọn fọrọ naa ṣe, ibọn lawọn naa fi fun wọn lesi.

Wọn nigba tawọn janduku naa ri i pe ọwọ awọn agbofinro le ju tiwọn lọ, lawọn kan fẹyin rin ninu wọn, ni wọn ba sa lọ, ṣugbọn mẹrinla lara wọn ti bogun rin, ọpọ lo si fara gbọta.

Anene ni ọwọ ba awọn kan lara wọn, awọn si ti taari wọn si ẹka awọn ọtẹlẹmuyẹ lati fun iwadii. O rọ awọn araalu lati fọkan balẹ tori ileeṣẹ ọlọpaa ko ni i tura silẹ titi tọrọ awọn janduku naa yoo fi di itan nipinlẹ Benue.

Leave a Reply