Awọn agbebọn pa ọkunrin to ni Falọla Hotel, n’Ileṣa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Inu ibanujẹ lawọn mọlẹbi Ọgbẹni Falọla Ọkẹ wa niluu Ileṣa bayii pẹlu bi awọn agbebọn ṣe da ẹmi rẹ legbodo lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Ọkunrin yii la gbọ pe o ni Falọla Hotel, to si tun maa n fi aga ati tabili rẹnti fun awọn oninaawo.

O n pada lọ sile rẹ lagbegbe Imọ, niluu Ileṣa, ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ Ọjọruu yii lawọn eeyan ọhun da ibọn bo mọto rẹ.

Nigba ti awọn eeyan yoo fi debẹ lẹyin ti iro ibọn naa lọ silẹ, wọn ba Falọla Ọkẹ to ti dagbere faye.

Ọmọ ijọ C&S to wa ni Idasa ni wọn pe Falọla, o si ti le lọmọ ogoji ọdun.

Gbogbo awọn ti wọn mọ ọn ni wọn jẹrii rẹ pe akinkanju to tẹpa mọṣẹ, ti ki i si ba ẹnikẹni fa wahala ni.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, ASP Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni iwadii si ti bẹrẹ lori rẹ.

Leave a Reply