Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Njẹ ẹ ti gbọ? Pe awọn agbebọnrin, ajinigbe, ti fi kun ọwọ ija wọn wayi, niṣe ni wọn pa ọlọpaa kan l’Ọjọruu, ọjọ karun-un, oṣu karun-un yii, niluu Abẹokuta. Wọn ji ọlọpaa keji ti wọn jọ n ṣiṣẹ gbe pẹlu awọn eeyan mẹta mi-in wọgbo lọ.
Koda, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, fidi ẹ mulẹ pe wọn pa ọlọpaa naa loootọ, wọn si gbe ikeji ẹ atawọn mẹta mi-in wọgbo lọ ni Ibara-Orile, nijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta.
Ohun ti a gbọ ni pe awọn tọkọ-taya kan ni wọn fẹẹ bẹrẹ oṣin ẹja, wọn si lọ si ileeṣẹ to n ri si eto ọgbin l’Abẹokuta, lẹka ti wọn ti n mojuto ẹja sinsin.
Ileeṣẹ yii fun wọn ni oṣiṣẹ wọn kan to kọṣẹ mọṣẹ, pe ko mu wọn lọ sibi ti wọn le lo lati bẹrẹ okoowo wọn. Awọn tọkọ-taya naa beere fun ọlọpaa to le daabo bo wọn bi wọn ba n lọ, a gbọ pe wọn si fun wọn ni ọlọpaa meji.
Afi bi wọn ṣe de Ibara-Orile ti oko naa wa ti awọn agbebọn kọ lu wọn. Wọn kọkọ yinbọn fun ọlọpaa kan, wọn pa a, wọn si gbe ẹni keji ẹ pẹlu awọn tọkọ-taya naa wọgbo lọ. Wọn gbe oṣiṣẹ ẹka imọ ẹja ti ileeṣẹ ijọba ni ko mu wọn lọ pẹlu.
Ṣugbọn o, Alukoro ọlọpaa Ogun sọ pe iṣẹlẹ yii ni ọwọ kan araale ninu, o ni biku ile ko ba pa ni, tode ko le pa ni. Oyeyẹmi ni wọn dena de awọn eeyan ti wọn kọ lu yii ni.
O lawọn to pa ọlọpaa ko ni i foju kan oorun mọ, wọn ti daran. O fi kun un pe awọn ti wa lẹnu ẹ bayii, awọn yoo mu wọn ṣinkun, awọn yoo si gba awọn ti wọn ko pamọ kalẹ lọwọ wọn.