Awọn agbebọn pa ọlọpaa kan, wọn ji oyinbo gbe lọ ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn afurasi agbebọn kan  ti ya bo ọgba ileesẹ CGC Construction Company, l’Opopona Shao-Oloru, nipinlẹ Kwara, wọn pa Insipẹkitọ Adebayọ Adeforiti to n ṣọ ọgba naa, wọn si ji oyinbo to jẹ agbasẹse ọmọ Chinese gbe lọ.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lo ti sọ pe iroyin ti de setiigbọ ileeṣẹ ọlọpaa pe awọn agbebọn ya bo ọgba ileeṣẹ kan to n ṣe ọna lagbegbe Shao si Oloru, ni ọjọ kẹji, oṣu Keje, ọdun yii, ti wọn si n yinbọn leralera. Wọn pa ọlọpaa kan, wọn si ji oyinbo Chinese kan gbe sa lọ.

Kọmiṣanna ọlọpaa, nipinlẹ Kwara, CP Tuesday Assayomo ti paṣẹ fun gbogbo awọn ẹṣọ alaabo nipinlẹ naa, ọlọpaa, fijilante ati awọn ọdẹ ibilẹ ki wọn tete sa ipa wọn lati doola oyinbo ti wọn ji gbe, ki wọn si mu awọn afurasi ẹni ibi ti wọn ṣiṣẹ buruku ọhun. Bakan naa lo kẹdun pẹlu mọlẹbi ọlọpaa ti wọn pa.

Leave a Reply