Adajọ ti ran Aafaa Muastapha to fipa ba ọmọ ọdun mẹjọ lo pọ l’Ekoo lẹwọn gbere

Onidaajọ H. O. Oshodi ti ile-ẹjọ giga ipinlẹ Eko to fikalẹ siluu Ikẹja, ti sọ Aafaa Isah Mustapha si ẹwọn gbere fun ẹsun pe o ba ọmọdebinrin ọdun mẹjọ kan lajọṣepọ.

Ninu ọrọ ọmọbinrin kekere ọhun, o ni afurasi ọdaran ọhun fipa ba oun laṣepọ nile ẹ lọdun 2017, nigba ti mama oun ran oun niṣẹ lọ sọdọ ẹ.

O ṣalaye pe niṣe ni Mustapha pe oun pada boun ṣe n lọ.

O ni, “Nigba to ku diẹ ki n de ile wa, ọkunrin naa pe mi pada pe oun fẹẹ ran mi lọọ gba alubọsa lọwọ mama mi, ki n si waa fun oun nisalẹ ile wa.

Mo si lọ soke lọọ gba alubọsa gẹgẹ bi wọn ṣe ran mi”.

Ọmọbinrin naa ṣalaye pe boun ṣe ko alubọsa fun afurasi ọdaran naa tan toun si fẹẹ pẹyin da bayii ni aafaa pe oun pada pe oun o ti i ṣetan pẹlu oun, iṣẹ ṣi ku toun fẹẹ ba oun jẹ.

“Ni wọn ba ni ki n wọnu ile awọn, ṣugbọn mo ni rara. Mo ṣaa pada wọle ki wọn ma baa sọ fun baba mi pe mo yaju si awọn. Bi mo ṣe wọnu ile tan ni wọn ba ni ki n bọ pata mi, ṣugbọn mo tun kọ jalẹ. Wọn ṣaa pada bọ ọ funra wọn, wọn si bọ ṣokoto tiwọn naa, ni wọn ba ba mi lajọṣepọ. Wọn fi nnkan ọlọmọkunrin wọn sinu temi, wọn si ba mi sun”.

O ṣalaye pe ọrọ naa di ariwo lasiko ti mama oun ko aṣọ oun sita lati fọ, ti wọn ri ẹjẹ nibẹ balabala.

Nigba to n ṣalaye ara ẹ, Mustapha ni loootọ loun ran ọmọ naa niṣẹ, ati wi pe oun kan ti ika oun bọ abẹ ẹ ni.

Agbejọrọ ọdaran, M. O. Ifarinde, rawọ ẹbẹ si Onidaajọ Oshodi lati ṣiju aanu wo onibaara oun gẹgẹ bo ṣe jẹ pe igba akọkọ ti yoo ṣe e ree.

Amọ Agbejọrọ fun olupẹjọ, B. T. Boye, rọ adajọ lati ma ṣe fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ẹjọ naa, ki wọn si dajọ naa gẹgẹ bo ṣe tọ, ko le da bii ẹkọ fawọn ọbayejẹ to ku.

Lẹyin ti adajọ ti yiri ọrọ ẹnu awọn agbejọro mejeeji atawọn ẹri ti wọn gbe siwaju ẹ wo, ẹwọn gbere lo ran ọdaran naa.

Leave a Reply