Awọn agbebọn to ji onisowo gbe n’llọrin n beere fun miliọnu mẹwaa naira

Ibrahim Alagunmu Ilọrin,

Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ to kọja lawọn agbebọn to dihamọra pẹlu ibọn ji gbajugbaja oniṣowo kan, Arabinrin Asiat Ishao, gbe lọ ni agbegbe Okoolowo, nijọba ibilẹ Guusu Ilọrin (South), nipinlẹ Kwara, awọn ajinigbe ọhun ti waa pe awọn mọlẹbi rẹ bayii, ti wọn si n beere fun miliọnu mẹwaa naira owo itusilẹ.

 

Asiat jẹ ọmọ agboole Okekere, nijọba ibilẹ Iwọ Oorun Ilọrin (West), nipinlẹ Kwara, ti awọn ajinigbe si ji i gbe ni alẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, lasiko ti arabinrin naa fẹẹ kuro lọọfiisi rẹ to wa ni adojukọ Bioraj Pharmacy, Okoolowo, Ilọrin, pẹlu ibọn. Ọjọ Abamẹta, Satide, ni awọn ajinigbe naa pe awọn mọlẹbi rẹ, ti wọn si n beere fun miliọnu mẹwaa naira owo itusilẹ.

Leave a Reply