Jọkẹ Amọri
Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe wọn ti tun pa eeyan marun-un mi-in niluu Mọdakẹkẹ, nipinlẹ Ọṣun. Adugbo Alapata, ni agbegbe Toro, ni wọn ni awọn agbebọn kan sadeede ya bo laaarọ kutu ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
Bi awọn agbebọn naa ṣe de adugbo yii ni wọn dana ibọn bolẹ, ti wọn si pa eeyan marun-un ti wọn ni ọmọ ilu Mọdakẹkẹ ni wọn loju ẹsẹ.
Bi wọn ṣe ṣiṣẹ buruku yii tan ni wọn sa lọ, ti ko si si ẹni to ri wọn mu.
Ọkan ninu awọn ọmọ ilu naa, Omideyi Adegbuyi, to ba akọroyin wa sọrọ lori foonu sọ pe lojiji ni iṣẹlẹ naa ba awọn nitori ko si ija tabi wahala kankan laarin ilu mejeeji ki iṣẹlẹ naa too waye.
O ni bii igba ti awọn ti wọn ṣiṣẹ naa tun fẹẹ da wahala silẹ laarin Mọdakẹkẹ ati Ileefẹ ni, nitori laarin ọsẹ meji ni wọn ti paayan bii mẹwaa yii. Eeyan marun-un naa ni wọn pa ni bii ọsẹ meji sẹyin, awọn yẹn n lọ si oko ni wọn lọọ da wọn lọna. Ko too tun di pe wọn tun pa awọn marun-un mi-in lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.